Take a fresh look at your lifestyle.

Àjíǹde : Arábìnrin àkọ́kọ́ pè fún ìfẹ́, àtẹ̀mọ́ra láàrin àwọn ọmọ Nàìjíríà

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

64

Arábìnrin Àkọ́kọ́ Nàìjíríà, Olurẹmi Tinubu, ti rọ àwọn ọmọ lẹ́yìn Kírísítì ní orílẹ̀-èdè láti ṣàfihàn ìfẹ́ sí àwọn alábágbé wọn, pàápàá jùlọ àwọn aláìní. Ó pe ìpè yìí nínú ọ̀rọ̀ ìfiránṣẹ́ rẹ̀ sí àwọn ọmọ Nàìjíríà.

O sọ pe, ‘ọdun Ajinde n ranwa leti ifarada agbara ifẹ, ifaragba, aimọ taraeni nikan Jesu Kirisiti,ati ireti ti jijinde rẹ mu ba ọmọ eniyan.

Bi a ṣe n ṣe ajọyọ Ajinde pelu awọn ololufẹwa, ọrẹ ati alabagbe, ẹ jẹ ki a ranti awọn ti ko ni, ki a si ṣaanu ati ran wọn lọwọ lọnakọna ti a ba lagbara.’

O tun wa pe awọn ara ilu lati ṣe afaragba fun ara wọn gẹgẹ bi ilana Ọdun Ajinde.

Comments are closed.

button