Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Tinuba, Adarí Chad ṣe àtúnyẹ̀wò lórí àjọṣepọ̀ ààbò

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

210

Ààrẹ Bọla Tinibu ti pinnu láti ṣàtúnyẹ̀wò lórí ìfọ̀rọ̀jomi toro ọ̀rọ̀ pẹ̀lú Chad láti kojú jàgídíjàgan àti adigunjalè ní Ẹkùn Lake Chad, tí ó sì ń fi ìdí ìpinnu Nàìjíríà múlẹ̀ láti ṣèmúdúró àjọṣepọ̀ ààbò láàrin àwọn méjèèjì.
O ṣe ipinnu yii ni Ọjọbọ, ni ile ijọba, ni Abuja, nigba ti o gbalejo Aarẹ Chad Muhamat Idriss Deby Itno, fun ifọrọjomi toro ọrọ to ṣe pataki lori aabo Ẹkun, idakọja aala to leto, ati idahun to tọ si awọn idunkẹkẹ ti n waye ni ẹka-Ẹkun naa.

O ṣe apejuwe abẹwo naa bii eyi to waye lasiko, Adari Naijiria ṣalaye pe ifọrọjomi toro ọrọ pẹlu Aarẹ Deby waye latari ipeninija aabo ti n koju Ẹkun naa, ti o si pe akiyesi pe Chad jẹ orilẹ-ede keji pataki ninu ajọṣepọ iṣe ologun ajọṣe ti o da ọpọlọpọ orilẹ-ede pọ (MNJTF).

Aarẹ Tinibu wa fikun un pe, orilẹ-ede mejeeji ti fẹnuko lati tẹramọ ajọṣepọ akitiyan lati koju jagidijagan, amukuroo idunkẹkẹ ipa, ati ikapa aabo ati ominira orilẹ-ede wọn.

O tun wa fidii ajọṣepọ ọlọjọ pipẹ to wa laarin orilẹ-ede mejeeji mulẹ, wipe awọn igbesẹ to n lọ lọwọ yoo da lori ipilẹ ti awọn adari to ṣaaju ti filelẹ lati ṣatunṣe lori iduruṣinṣin, ilọsiwaju, ọrọ-aje ati idagbasoke Ẹkun.

Comments are closed.

button