Ìsìn Ìbúra sípò Ààrẹ Àti Igbákejì Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàíjíríà ọdun 2023 wáyé ní ilé Ìjọsìn ni ecumenical Centre nílùú Abuja ní ọjọ́ kejidinlọgbọn, oṣù karùn-ún, ọdun 2023
Àwọn ènìyàn pàtàkì lo wa ni bi ìsìn yii, Lára àwọn ènìyàn pàtàkì tí ó wà níkàlẹ́ nílé Ìjọsìn ni:
Olóyè Iyiola Omisore, ògbòńtarìgì, ọ̀kan lára ẹgbẹ́ òṣèlú APC.

Asofin ìyáàfin Oluremi Tinubu,aya ààrẹ tuntun Hamed Bola Tinubu.

Ààrẹ àná lásìkò ìjọba ológun lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà,Yakubu Gowon

Boss Mustapha, Akọ̀wé àgbà fún ìjọba àpapọ̀ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Ìgbákejì ààrẹ tó ń kógbá wọlé,Yemi Osinbajo, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ

Archbishop John Praise lo sọ Ọ̀rọ̀ iyànjú, O sọ pe ètò ọ̀rọ̀ ajé orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí doríkòdò, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ènìyàn ń gbé nínú ìbẹ̀rù sùgbọ́n agbára Ọlọ́run ju gbogbo rẹ̀ lọ.
Àwọn ohun àràmàǹdà àti àṣà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí a ní ni agbára wa.
Àsìkò àti ìgbà ọ̀tun ti dé báyìí.
Ẹ jẹ́ kí a gbàgbé èdè -àyedè tó bá wà láàárín wa.
Kí a sí fọwọ́sowọ́pọ̀ láti máa wá ìsọkan àti ìtẹ̀síwájú Orile èdè Nàìjíríà.
Ẹ jẹ́ kí á fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ìjọba tuntun àti àwọn ikọ̀ rẹ̀ nínú àwọn ìgbìyànjú wọn.
Kí ijọba tuntun rí ì pé ẹlẹ̀sìn onígbàgbọ I
Ìyẹn Kirisiteni ni wọ́n fi ṣe alàkóso tàbí adarí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà.
Oníwàásù tún wà rọ àwọn ènìyàn láti máa yanjú àwọn ohun tó bá ń dùn wọ́n lọ́kàn tàbí ohun tí wọ́n bá ń fẹ́ lọ́wọ́ ìjọba ní ìtùbí-ìnùbí
Kí ìjọba tuntun yii rí i pé wọn mú gbogbo ìlérí tí wọ́n ṣe fún àwọn ènìyàn lásìkò ìpolongo ètò ìdìbò wọn sẹ.
Kí wọ́n môjútó ètò àgbẹ̀ ati ọ̀rọ̀ àìnísẹ́ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà
Lẹyin ti a gbọ ìwàásù, Asofin Oluremi Tinubu naa bọ sta láti sọ̀rọ̀ báyìí.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ìyáàfin Oluremi Tinubu ní:
Ọkọ rẹ̀, Ahmed Bola Tinubu fẹ́ láti wá níbi yìí sùgbọ́n nítorí ìdíwọ́ kan tàbí ìkejì.
ìkejì,wọn kò leè wa níbi yìí
Asíwájú Bola Tinubu ti di ọmọ ọdún mọ́kànlélàádọ́rin(71 years ).
Ètò ìjọba tiwa-n-tiwa ẹlẹ́keje ni a wà yìí.
Eléyìí túmọ̀ sí ìgbà pípé, ìgbà ọ̀tun.
Ìgbà tàbí àsìkò tó yẹ kí gbogbo ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fọwọ́sowọ̀pọ̀ fún ìrètí tuntun.
Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà yìí jẹ ti gbogbo wa, kìí ṣe ti ẹnìkan ṣoṣo.
Ọlọ́run ti bùkún mọ̀lẹ́bí mi, nítorí náà, àwa ko nilo owó Nàìjíríà láti fi là.
A ó gbìyànjú láti ṣe ohun tó tọ, nítorí náà a nílò ádùrá gbogbo ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti leè se àṣeyọrí.

Ìgbákejì ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàíjíríà, Yemi Osinbajo naa bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ tirẹ̀ báyìí.
Bí ìjọba ààrẹ Mùhámádù Buhari se ń kógbá wọlé ti ìjọba Ahmed Bola Tinubu sì ń wọlé wa, a nílò ìfẹ́ àti ìsọ̀kan láti mú orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tẹ̀síwájú.
Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ láti bùkún orílẹ̀ èdè tí ó bá tẹ̀lê ìwà òdodo.

George Ọláyinká Akíntọ́lá.
Leave a Reply