Take a fresh look at your lifestyle.

N kò Ní Já Yin kulẹ̀ Nípa Títẹ̀lé Ipa Ọ̀nà Ìtẹ́síwájú.- Seyi Makinde

0 264

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti fi da àwọn èèyàn Ìpínlẹ̀ náà lójú wi pe òun kòní já wọn kulẹ̀ nípa titẹle ipa ọna ìtẹ̀síwájú, nígbà tí aṣáájú ẹsin gba Gómìnà níyànjú láti wá ojú Ọlọrun nígbà gbogbo.

Makinde lo sísọ lójú ọrọ yìí ni asiko ìsìn idupẹ eléyìí to waye ni ilé ìjósìn Sword of the Spirit Ministries, to kalẹ sí Fafiti Cornerstone ni agbègbè Olaogun, ni ìlú Ìbàdàn tíì ṣe olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ni Ẹkùn Gúsù Iwọ Oòrùn Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Nígbà tí o n ba àwọn olùjọsìn sọrọ, Makinde lo àsìkò náà láti fi da àwọn èèyàn Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lójú pé ìṣèjọba òun yóò máa ṣe àgbéyẹ̀wò ọdọọdún láti ríi dájú pé o mu èròngbà lori Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ rẹ ṣẹ.

Gẹgẹ bíi o ṣe ṣèlérí, o ní Ìdàgbàsókè Ọlọjọ pipẹ tí Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lati ọdún 2023 – 2027 yóò gbéra sọ lati ọjọ àjé, ọjọ Kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù kàrún. O wá fi kún ọrọ rẹ pé: “Nítorí o jẹ ifẹ Ọlọrun láti jẹ kí ìṣèjọba ẹlẹẹkeji ṣeé ṣe, Ọlọrun náà ni yóò tẹ Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ sí ipa ìlọsíwájú.”

Nígbà tí o bojú wo àwọn àṣeyọrí re ni iwọn ọdún mẹrin sẹyi Makinde ṣèlérí láti túbọ̀ mọ le ìpìlè iṣẹ réré to ti fi le’lẹ. O wá tun fi àsìkò náà rọ gbogbo èèyàn Ọlọrun àti àwọn aṣáájú ẹsin láti máa gbàdúrà fún àṣeyọrí ìṣèjọba rẹ.

Nígbà tí o n wàásù, ẹni tíì ṣe Ààrẹ Ẹgbẹ Ọmọ lẹyin Kristi, Ẹni-ọwọ Supo Ayokunle, gba Makinde níyànjú láti máa wá ojú Ọlọrun nínú gbogbo idawọle rẹ, tó sì tún rọ̀ ọ́ láti ní ìgboyà nípa ṣíṣe ohun ti yóò la ipa rere lórí àwọn èèyàn Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Bákan náà ní, ẹni tó jẹ Olùdásílẹ̀ ilé ìjósìn Sword of the Spirit, Bisobu Wale Oke lu Makinde l’ọgọ ẹnu nipa nini se pèsè eto iṣejọba daradara ni saa akọkọ rẹ, tí o sì gbàá níyànjú láti tubọ máa mọ le ìpìlẹ réré síwájú síi

O wá gbàdúrà fún Makinde fún àṣeyọrí rere gẹgẹ bí sáà ẹlẹẹkeji yóò ṣe gbéra sọ lati ọjọ Àjé, ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n.

Abiola Olowe
Ìbàdàn

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button