Ìyanṣẹ́lódì jákèjádò orílẹ̀-èdè: Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ Nàìjíríà ti àwọn òṣìṣẹ́, àlejò mọ́ ìta ilé ìgbìmọ̀
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìgbìmọ̀ àti àwọn àlejò tó fẹ́ wọlé tàbí tó fẹ́ jáde nínú ọ́fíísì láàrín ibùdó ilé ìgbìmọ̀ kò ráyè láti agogo mẹ́fà òwúrọ̀, Ọjọ́ọ́rú, ọjọ́ kẹẹ̀dógún, oṣù kọkànlá, 2023.

Oni ni yoo jẹ ọjọ keji, ti awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ (NLC) ati ẹgbẹ oni krakata ni Naijiria (TUC) ti yabo ile igbimọ lati fi idi iyanṣelodi jakejado orilẹ-ede lori ede aiyede pẹlu ijọba Naijiria mulẹ.
Ṣugbọn awọn Asofin ti o ti raye wọle si ile igbimọ mejeeji ni ọjọ Iṣegun, ọjọ kẹrinla, oṣu kọkanla, 2023 ti n ba ipade wọn lọ, ni asiko ti iroyin yii n bọ sita.

NLC ni o pa aṣẹ iyanṣẹlodi yii lẹyin ti ipade igbimọ alasẹ apapọ ti waye ni ipari ọsẹ, ti o si n pa laṣe fun gbogbo ti o wa labẹ ẹgbẹ naa ṣe bẹ.

NLC ati igbimọ oni katakara (TUC) ti gbe igbesẹ yii lẹyin ti wọn jumọ ṣe ipade ni Abuja, nitori ifọwọ ọla gbaniloju ati aima fun oṣisẹ ni ẹtọ wọn, ikọlu aarẹ NLC, Comrade Joe Ajaero, lasiko ifẹhonuhan ni ipinlẹ Imo ati bi ijọba ṣe tẹsiwaju ni kikọ imuṣẹ awọn adehun kan ti wọn ti jọ fọwọ si.
Leave a Reply