Take a fresh look at your lifestyle.

Barcelona, Tottenham Bẹ̀rẹ̀ Ifá-Ń-Fà Lórí Àgbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà, Ndidi

0 264

Tottenham Hotspur tí múra láti kojú ìkọ àgbábọ́ọ̀lù Barcelona látí rá àgbábọ́ọ̀lù ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Wilfred Ndidi bó tí n gbèrò látí tẹ̀síwájú kúrò nínú ìkọ Leicester City.

Àdéhùn láàrín Ndidi pẹ̀lú Leicester yóò wà sí òpin ni ìparí sáà igbábọ́ọ̀lù yìí, ṣùgbọ́n bóyá Maresca tó jẹ́ alákóso ìkọ náà yóò nílò àgbábọ́ọ̀lù yìí tí wọ́n bá peregede láti kópa nínú ìdíje ‘English Premier League’ ní sáà tó ń bọ̀.

Ndidi tí ṣoju ìkọ náà ni ìgbà mẹẹdogun nínú gbogbo ìdíje tó sì mí àwọ̀n ní ẹẹmẹta pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ mẹ́rin. Èyí tí rán Leicester city lọ́wọ́ láti wà ní òkè tábìlì.

Barcelona ní á tí rí àkọsílẹ̀ pé wọ́n ní ìṣòro ìnáwó, ló tí ń gbìyànjú láti rá àgbábọ́ọ̀lù ‘Super Eagles’ náà ní ìparí sáà yìi.

Lábẹ́ ìdájọ́ Bosman, Barcelona yóò ní ànfàní láti bá àgbábọ́ọ̀lù yí sọ̀rọ̀ àdéhùn ní Oṣù Kíni l’ojuna láti gbá àgbábọ́ọ̀lù náà.

Sibẹsibẹ, kìí ṣé ẹgbẹ́ Barcelona nìkàn ló n’ifẹ sí àgbábọ́ọ̀lù ọmọ Nàìjíríà yìí, bí ìròyìn tún ṣé jáde pé oluṣakoso Tottenham, Ange Postecoglou, tún tí ṣé àfihàn ìfẹ rẹ̀ sí Ndidi. Làkókò tí Bayern Munich, Atletico Madrid àti Juventus náà tún ṣé ń ṣé abojuto ọmọ ọdún mẹ́rindínlọgbọ́n (26) náà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button