Ìgbìmọ̀ Olómìnira tí ń mójútó ètò ìdìbò lórílẹ̀-èdè, INEC, ní ìpínlẹ̀ Kogi , Àringbùngbùn Nàìjíríà ti bẹnu àtẹ́ lu bí àwọn ènìyàn kan ṣe ya lu olú ilé iṣẹ́ rẹ̀ ní Lokoja, olú ìlú, tí wọ́n sì dí gbogbo ọ̀nà tó wọ ọ̀fíísì láti ṣe ìdíwọ́ fún àwọn òṣìṣẹ́ tí yóò ṣiṣẹ́ òòjọ́ wọn.
Alaye iroyin kan ti Kọmiṣọna adari eto idibo ni ipinlẹ naa, Hale Gabriel Longpet buwọlu sọ pe “igbogunti naa tun ṣe idiwọ fun awọn adajọ agba ti n ṣoju awọn ẹgbẹ oṣelu ti o kopa ninu aṣekagba idibo gomina to waye laipẹ yii lati ṣamojuto awọn iwe/eroja ti wọn lo lasiko idibo”.
Longpet ṣalaye pe ọpọlọpẹ awọn ologun Naijiria to dasi ọrọ yii, lo jẹ ki gbogbo rẹ rọlẹ ni olu ile iṣẹ naa ti “awọn ile iṣẹ alaabo si ti fi da wa loju pe awọn yoo pẹtu si agbegbe naa”.
REC tun wa mu da gbogbo awọn tọrọ kan ati awọn olupẹjọ loju pe ile iṣẹ igbimọ naa ti ipinlẹ Kogi State office pinnu lati pese anfaani ti ko ni idiwọ si awọn ohun elo fun ipẹjọ ẹsun wọn.
A o ranti pe lati ọjọ kọkanla, oṣu kọkanla 2023, ti wọn ti kede esi ibo gomina, ti wọn ti kede ẹgbẹ APC ti n ṣejọba gẹgẹ bii olubori ni, ifẹhonu han ti n waye ni olu ile iṣẹ INEC ni Abuja fun ati ikoju esi naa.
Leave a Reply