Ilé-igbimọ Aṣòfin Nàìjíríà Ti Gba Ètò Ìṣúná Tó Dín Díẹ̀ Ní Àádọ́rin Tíríníọ̀nù Náírà, N68.3Trn Ti Ọdún 2026 Wọlé
Ilé-igbimọ aṣofin Naijiria ti gba Isuna ọdun 2026 wọlé lẹhin ti o ti fi owo tó lè diẹ ni Tirilonù,N9.3 mẹsan Naira kun, bi Aare Bola Tinubu ti béèrè fún bí àfikún, ti o mu iye naa wa si owó to din diẹ ni Àádọ́rin Tirinionu Náírà, N68.3Trn.
Yatọ si ifọwọsi ibeere aarẹ, Ile-igbimọ aṣofin tun mu isuna apapọ náà pọ si nipasẹ fifi etalelogun-le-legbeta Biliọnu Naira, N623 bilionu kun un.
Ile-igbimọ aṣofin sun apapọ owo eto isuna apapọ lati N67.7 trillion, si N68.323 trillion gẹgẹ bi aarẹ ti beere,
Owó Ìṣúná náà ni wọn fọwọsi lẹhin ti ọpọlọpọ awọn aṣofin ti fọwọsi nipasẹ ibo olóohùn.
Nigba to sọrọ lẹhin igbawọlé owo isuna naa, Aarẹ Ile-igbimọ aṣofin Naijiria, Sẹnetọ Akpabio, dupẹ lọwọ awọn ẹlẹgbẹ rẹ, paapaaju awọn Kọmití lori Isuna ni awọn ile-igbimọ aṣofin mejeeji, fun side iṣẹ laije ki o t wọn lati rii daju pe Isuna ọdun 2026 ti di ìtẹ́wọ́gbà.
Bakannaa pẹlu bibá awọn oniroyin lẹhin Apejọ naa, Alaga Igbimọ Ile-igbimọ aṣofin lori Isuna, Sẹnetọ Olamilekan, rawọ ẹ̀bẹ̀ si gbogbo awọn ọmọ Nàìjíríà lati tẹsiwaju lati ṣe atilẹyin fun awọn atunṣe eto-ọrọ aje ti Aare Bola Tinubu, eyiti o sọ pe o n mu awọn abajade rere jade.
Bakannaa ni sisọ pẹlu awọn oniroyin lẹhin Apejọ naa, Alaga Igbimọ Ile-igbimọ aṣofin lori Isuna, Sẹnetọ Olamilekan, rawọ si gbogbo awọn ara ilu Naijiria lati tẹsiwaju lati ṣe atilẹyin fun awọn atunṣe eto-ọrọ aje ti Aare Bola Tinubu, eyiti o sọ pe o n mu awọn abajade rere jade.
Temitọ́pè Òbísẹ̀san