Ilé-ìfowópamọ́, AATIF kéde iye owó mílíọ́ọ́nù mẹ́èdọ́gbọ̀n dọ́là láti pèsè ìdókòwò oun ọ̀gbìn lọ́pọ̀
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ní ìlà pẹ̀lú àwọn akitiyan ìjọba láti mú kí gbígbé oúnjẹ wọ̀lú láti ìlu òkèèrè dínkù àti pípèsè oúnjẹ lọ́pọ̀ yanturu,ilé-ìfowópamọ́ Union ti Nàìjíríà àti àjọ adúláwọ̀ tó ń mójútó owó oun ọ̀gbìn àti kátàkárà ìdókòwò,AATIF,ti kéde pé ilé-ìfowópamọ́ náà ti ṣàgbékalẹ̀ iye owó tí ó tó mílíọ́ọ́nù mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n dọ́là pẹ̀lú ìlànà AATIF láti mú ìpinnu fífẹ ìdókòwò oun ọ̀gbìn lójú wá sí ìmúṣẹ.
Gẹ́gẹ́ bí àlàyé kan, ìgbówọlé AATIF yóò ṣe àtìlẹyìn fún gbígbilẹ̀ ilé-ìfowópamọ́ Union àti ìtànkálẹ̀ sí kátàkárà oun ọ̀gbìn Nàìjíríà, pẹ̀lú àtìlẹ́yìn pàtàkì láti túnbọ̀ ṣe dáradára àti tẹ̀sìwájú lórí ipa rẹ̀ nínú ẹ̀ka náà.
Gẹ́gẹ́ bí apákan owó àdéhùn ,àgbéga àti ìtànkiri yóò dé bá àwọn ọjà ògbìn tuntun ,tí wọn yóò sì náwó lórí àwọn ìṣòwò oun ọ̀gbìn náà sii.
Leave a Reply