Take a fresh look at your lifestyle.

Ikọ̀ Ọmọ Ogun Sọ Agbára Àwọn Agbésùòmí Di Òtu Bántẹ́ Ní Ọ̀nà Kàdúná Sí Záríà

0 297

 

Ikọ̀ ọmọ ogun àpapọ orílẹ̀ èdè yìí ti sọ agbára àwọn agbésùmọ̀mí méjì ní ọ̀nà Kàdúná sí Záríà ní ìjọba ìbílẹ̀ Igabi  ti ìpínlẹ̀ Kàdúná di òtu bántẹ́.

Eléyìí jẹyọ nínú atejade ti wọ́n fọwọ́sí láti ọwọ́ kọmísọ́nà nipa aabo abele ati ile ti ipinle naa, ọ̀gbẹ́ni Samueli Aruwon to lu jade sọ́dọ̀ àwọn akoroyin ni ilu Kaduna.

Gẹ́gẹ́bí kọmísọ́nà náà se sọ, Ìjọba Ìpínlẹ̀ náà gba ìròyìn ayọ̀ náà pẹ̀lú inu dídun, àwọn sị́ì gbóríyìn àti òsùbà fún àwọn ọmọ ologun naa fun kikoju awon agbésùmọ̀mí náà ní kíákíá, ní wàrànsesà.

Ìjọba si fi kun pe awon fe ki  iru akitiyan bẹ́ẹ̀ máa tẹ̀ẹ́síwájú lati ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ ologun, awọn eniyan si tun leè pè sí àwọn nọ́ọ́mbà ìbáraẹnisọ̀rọ̀ yìí “09034000060 ati 08170189999.” lati ta àwọn ọmọ ológun lólobó nitori awon ọ̀daràn agbésùmọ̀mí kan sálọ pẹ̀lú oró ọta ìbọn lára wọn.

Ọ̀gbẹ́ni Aruwon jẹ́ kó yé àwọn ènìyàn pé àwọn ọmọ ogun yóò sì tún máa káàkiri láti dáàbòbò àwọn olùgbé agbègbè náà.

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button