Take a fresh look at your lifestyle.

Ìdíje U.S Open: Jabeur Di Ọmọ Adúláwò Àkọ́kọ́ Tó Máa Wọ Ipele Tó Kángu Sí Àsekágbá

0 372

 

Jabeur di ọmọ adúláwò àkọ́kọ́ tó wọ Ipele tó kángu sí àsekágbá. Ó borí alátakò rẹ̀ tó ń jẹ́ Tomijanovic ní ìgbà mẹ́rin ní àpapọ̀ (6-4, 7-6) abbl. ní pápá ìseré Arthur Ashe.

Ó ti kọ́kọ́ fi ìtàn balẹ̀ nípa bíborí Serena Williams ní ipele kẹ́ta.

Jabeur máa kojú alátakò míràn,Caroline Garcia tí òun náà ti borí ọmọ ọdún méjì-dín-lógun ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà tó ń jẹ́, Coco Gauff.

Jabeur sọ̀ pé, àseyọrí yìí túmọ̀ sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan fún òun, yóò sì tún jẹ́ kóríyá fún àwọn ọ̀dọ́ eléré ìdárayá ní ilẹ̀ Adúláwọ̀.

Jabeur ati Tomljanovic jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́-tímọ́, wọ́n sì máa ń dì mọ́ ara wọn láti kí ara wọn nígbàkígbà tí wọ́n bá gbá bọ́ọ̀lù tán. Jabeur jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Tunisia tó borí eré Wimbledon láìpẹ́ yìí.

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button