Take a fresh look at your lifestyle.

Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ṣe ìtanijí fún àwọn olùgbé lórí lílo àwọn Dókítà aláìmọ̀kan

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 213

Ìjọba ìdàgbàsókè agbègbè Mosan-Okunọla (LCDA), ní ìpínlẹ̀ Eko, ti ṣe àgbékalẹ̀ ètò ìtanijí fún àwọn olùgbé lórí ewu tó wà nínú lílo àwọn Dókítà aláìmọ̀kan fún ìtọ́jú.

Alaṣẹ Alaga igbimọ naa, Ọmọ Ọba Ọlabisi Adebajo, sọ nibi eto naa pe lilo àwọn Dókítà aláìmọ̀kan tabi awọn ti ko kunju osunwọn fun itọju le yọri si ọna to lewu.

Ọgbẹni Dayọ Ọṣinnọwọ, igbakeji alaga igbimọ naa, ti o ṣoju Adebayọ, sọ pe awọn eniyan pupọ n lo awọn Dokita Alaimọkan nitori pe wọn ko ni agbara lati san owo igbatọju ni ile iwosan.

O sọ pe, Ijọba ipinlẹ, lara akitiyan rẹ lati jẹ ki eto itọju ara to muna doko wa ni ikapa awọn olugbe, ti ṣe agbekalẹ eto dojutofo ilera to pa dandan, “Ilera Eko Health Scheme” ní ipinlẹ naa.

Labẹ eto yii awọn ti yoo ṣe le ni anfaani si itọju ni awọn ile iwosan ti wọn fọwọ si ni ibikibi ni agbegbe ipinlẹ naa.

Ipinlẹ Eko ni ojuṣe lati ri pe gbogbo olugbe ni o forukọ silẹ fun eto idojutofo ilera ni ipinlẹ naa.

Eto yii yoo wa fun ọdun kan lẹyin ti wọn yoo tun ṣe eto owo dida miiran, fun ọdun miiran.

 “Awọn to forukọ silẹ fun eto naa yoo ni anfaani si itọju ni awọn ile iwosan to ba wu wọn. Awọn eniyan ti o ju Miliọnu kan lo ti fi orukọ silẹ bayii.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button