Take a fresh look at your lifestyle.

Ìgbákejì Ààrẹ Kí Bola Tinubu Kú Oríìré Fún Ìdìbò Yàn Gẹ́gẹ́ Bí Ààrẹ Túntún

Lekan Orenuga

0 500

Ìgbákejì Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Yemi Osinbajo tí kì Ààrẹ túntún tí á dìbo yàn nínú ìdìbò Ààrẹ 2023, Bola Ahmed Tinubu.

Olùrànlọwọ pàtàkì ìgbákejì Ààrẹ náà lórí ètò Ìròyìn àtí Ìpolongo, Laolu Akande sọ èyí dì mímọ̀ ní Ọjọ́rú.

Ìgbákejì Ààrẹ kọ̀wé nínú lẹta kàn pé, “Mó kí olùdíje lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ wà, All Progressives Congress, APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu, kú oríire lórí bí ó ṣé ṣẹgun nínú ìbò Ààrẹ ọdún 2023, àtí bí wọ́n tí kéde rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ tí wọ́n dìbo yàn tí Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.”

“Mo tun kí Sẹnetọ̀ Kashim Shettima kú oríìré fún ìkéde rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ìgbákejì Ààrẹ nínú Ìdìbò náà.”

Tún kà nípa: Mínísítà Ìdárayá Kí Ààrẹ Túntún Tí Á Fibò Yàn Kú Oríìré

Lẹyìn náà ló gbà Akọ̀wé ìjọba àpapọ̀ ní iyànjú láti kọ̀wé ṣé ifidunu hàn tí Ìgbìmọ̀ àwọn Aláṣẹ Orílẹ̀-èdè yìí èyí tí ìgbákejì Ààrẹ dárí rẹ̀.

Lẹyìn ìpàdé yí ní Ìgbákejì Ààrẹ náà lọ́ darapọ̀ mọ́ àwọn àkẹgbẹ́ rẹ̀ tí ẹgbẹ́ òṣèlú APC níbí tí Àjọ INEC tí fún olúbóri ètò ìdìbò náà ní ìwé-ẹri gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ tí á fibò yàn ní ilé iṣé ikóbòjọ́ tó wà ní International Conference Centre ní Abùjá, Olú-ìlú Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button