Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹ gbé Abba Kyari lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n Kuje- Adájọ́ Emeka Nwite

0 238

Ilé-ẹjọ́ giga to wa niluu Abuja, federal High Court ti pasẹ pe ki wọn maa gbe Abba Kyari to jẹ igbakeji kọmisọna ti wọn gba isẹ́ lọwọ lori ẹ̀sùn  gbígbé òògùn olóró lọ si ọgbà ẹ̀wọ̀n Kuje to wa niluu Abuja.

Àjọ  NDLEA fi ẹ̀sùn gbigbe oogun oloro kokeni (cocaine) kan  DCP Abba Kyari ati awọn ọmọ lẹyin rẹ mẹrin pe wọn lọwọ ninu oogun oloro ti ìwọǹ rẹ to 21.25kg, ti ajọ NDLEA gba lọwọ Umeibe ati Ezenwanne.

Adajọ àgbà, Emeka Nwite lo pasẹ yii pe ki ajọ tó n gbogun ti mimu ati gbigbe oogun oloro, iyẹn  NDLEA maa gbe Abba Kyari lọ si ọgbà ẹ̀wọ̀n to wa ni Kuje ,lẹyin adajọ kọ̀ pé ki wọn gba ìtanràn, iyẹn béèlì rẹ̀.

 

Ile-ẹjọ tun fi kún un pe àwọn ẹ̀rí  to wa niwaju wọn nipa Abba Kyari ko lee jẹ ki wọn gba beeli Abba Kyari ati awọn ẹmẹ̀wà rẹ̀.Bakan naa, ni ile-ẹjọ tún kọ̀ lati gba beeli ACP Sunday Uba, Inspector Simon Agirgba ati Inspector John Nuhu.

Amọsa, adájọ́ àgbà, Emeka Nwite, wa pasẹ pe ki  awọn agbẹjọrọ ijọba ati agbẹjọro fun Abba Kyari  tètè se kiakia lori igbẹjọ ọhun , bo tilẹ jẹ pe ilé- ẹjọ ́tún sún ìgbẹ́jọ́ naa si ọjọ́ kejidinlọgbọn osu kẹrin, ọdun yii (28-04-22).

Ti a o ba gbagbe pe, Umeibe ati Ezenwanne , ti wọn wa lara awọn ti ajọ NDLEA gbe wa pẹlu Abba Kyari wa sile ẹjọ́ , tí awọn mejeeji  si sọ fun ile-ẹjọ pe awọn jẹ̀bi ẹsun ti ajọ NDLEA fi kan wọn, ni eyi ti ile-ẹjọ si pasẹ pe ki awọn agbẹjọrọ ti wọn fi ẹsun kan ati agbẹjọro ijọba se kiakia lori igbẹjọ naa, ki wọn le gba ìgbẹ́jọ́ wọn.

Agbẹjọrọ agba fun Abba Kyari, Kanu Agabi (SAN) wa tako ẹjọ naa pe , niwọn igba ti igbẹjọ si n lọ  lọwọ , ni eyi ti o ni se pẹlu onibara rẹ, Abba Kyari , ko ni dara pe ki wọn da ẹjọ́ fun Umeibe ati Ezenwanne.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button