Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ labẹ ìsàkóso Gómìnà Seyi Makinde ti da àwọn òṣìṣẹ́ eleto ààbò sí àgbègbè Ipapo/Iseyin tó wà ní ẹkùn ìdìbò Àríwá ìpínlè Ọ̀yọ́ latari ijinigbe tó wáyé ní agbègbè náà ni ọjọ Àbámẹ́ta.
Ìjọba wá rawọ ẹbẹ sí àwọn olùgbé agbègbè náà láti máṣe mi ọkàn nitori awon agbe mẹrin tí àwọn agbebon ji gbé ni agbègbè Ipapo/Iseyin ni ìpínlè Ọ̀yọ́ to wà ní ẹkùn gúsù iwọ oòrùn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Nínú atẹjade ti Komisana tó n ri sí Ètò Ọgbin àti Alumọni ni ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọgbẹni Adeniyi Adebisi je kí o di mímọ nínú atẹjade to fi síta pé iko ẹṣọ aláàbò ti lo sí àgbègbè náà láti kún àwọn ẹṣọ aláàbò tó wà níbẹ tẹlẹ lọwọ.
Bákan náà ni Kọmisana fún Irọyin, Àṣà àti Ìrìn Àjò Afe ni ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ọ̀mọ̀wé Wasiu Olatubosun sọ nínú atẹjade ti o fi sowo sí àwọn oniry pé ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti pinnu láti sa gbogbo ipa wọn láti rí wípé o gba àwọn èèyàn náà padà kúrò ní àkàtà àwọn ajinigbe ohun.
Olatubosun wa tun tẹnu mọ pé, iko ọmọ ológun ilẹ̀ náà yóò darapọ mọ àwọn ẹṣọ aláàbò yòókù lati rí dájú pé wón gbà àwọn èèyàn náà silẹ ki wọn sì tún mú àwọn amookunseka náà lati fojú wi iná òfin.
Abiola Olowe
Ibadan
Leave a Reply