Take a fresh look at your lifestyle.

Alákóso Orílẹ-èdè Japan Yóò Ṣé Àbẹwò Sí Akẹgbẹ Rẹ̀ Tí Orílẹ-èdè Australia

0 437

Alákóso orílẹ-èdè Japan, Kishida Fumio yóò ṣé àbẹwò sí akẹgbẹ rẹ̀ tí orílẹ-èdè Australia Anthony Albanese ní oṣù yìí ní ìlú Perth.

Alákóso Anthony Albanese kó fúnni ní ọjọ́ pàtó fún àbẹwò náà ṣùgbọ́n o sọ pé ìpàdé pẹ̀lú akẹgbẹ òun tí orílẹ-èdè Japan tí wá ní ṣẹlẹ.

“Èmi yóò gbàlejò Alákóso orílẹ-èdè Japan ní ìlú Perth ní ọsẹ méjì sí àkókò yíì ni ìpàdé àjọṣepọ̀ orílẹ-èdè méjèèjì. Dípò kí a ṣé ìpàdé náà ní Canberra tabi Melbourne.”

Nígbàtí o ń sọ̀rọ̀ ní orílẹ̀-èdè Japan, Kishida sọ fún àwọn oníròyìn pé ìpinnu lórí àbẹwò náà kò tí fí ẹsẹ múlẹ̀.

“Mó tí ń gbìyànjú láti ṣé àbẹwò sí Australia ní kété tí gbogbo ètò bá ti tò, ṣùgbọ́n kò tíì sí ìdánilójú.”

Olugbohunsafẹfẹ tí orílẹ-èdè Japan NHK jábọ̀ ní ọsẹ tó kọjá pé àbẹwò náà ní yóò wáyé ní ìparí Oṣù Kẹwàá.

Lekan orenuga

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button