Jama’at Mùsùlùmí Ahmadiyya ní Nàìjíríà, tí pé fún àlàáfíà àtí ìdádúró ogún ní Gaza.
Ẹgbẹẹgbẹrun ènìyàn pẹ̀lú àwọn Obìnrin àtí àwọn ọmọdé tí kú nínú ìjà láàrin àwọn ológun Ísráẹ́lì àti Hamas ní Oṣù díẹ̀ sẹ́yìn.
Amir tí Jama’at Mùsùlùmí Ahmadiyya ní Nàìjíríà, Azeez Alatoye, ṣé ìpè náà làkókò tó ń ṣí Ilè-ìwòsàn Mùsùlùmí Ahmadiyya tó wà ní Ìpínlẹ̀ Kano ní Òpópó-ọ̀nà Zaria, tí wọ́n ṣé láti pèsè ìtọjú ìlera fún àwọn aráàlú.
O tún ló ànfààní náà látí pé fún ètò àlàáfíà ní àwọn àgbègbè kàn ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó ní ìpèníjà ààbò.
Alatoye sọ pé ẹsìn Islam jẹ́ ẹsìn àlàáfíà tí kò f’ayé gbá jagidijagan.

Ní àpá tirẹ, Emir tí Kano, Aminu Ado Bayero, gbóríyìn fún ẹgbẹ́ náà fún iṣẹ́ náà, èyí tó sọ pé yóò jẹ́ ìwúlò ọlọ́jọ́ pípẹ́ fún àwọn ènìyàn àgbègbè náà.
Ilè-ìwòsàn tí ẹgbẹ́ Mùsùlùmí Ahmadiyya àkọ́kọ́ ní wọ́n dá sílẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Kano ní ọdún 1962 tó ní ẹ̀ka ójú, eyín, àtí gbogbo ará tó wà ní Bompai, Kano, Nàìjíríà.