Take a fresh look at your lifestyle.

Ìpínlẹ̀ Anambra Ṣí Gbọ̀ngán Ilé-iṣẹ́ Ọlọ́pàá Olówó Nlá Kàn

392

Kọmíṣọ́nà Ọlọ́pàá ní Ìpínlẹ̀ Anambra, Ọ̀gbẹ́ni Aderemi Adeoye, tí ṣiṣọ́ lójú gbọ̀ngán Ilé-iṣẹ́ Ọlọ́pàá olówó nlá kàn ní Ẹ̀ka ọlọ́pàá Ozubulu, ní ìjọba ìbílẹ̀ Ekwusigo ní ìpínlẹ̀ náà.

Olóyè Alloysuis Ikegwuonu, alága àtí olùdásílẹ̀ Ebubechukwuzo Foundation ní o kọ́ ilé nlá náà.

Nígbà tí wọ́n ṣiṣọ́ lójú ilé náà, Ọ̀gbẹ́ni Adeoye ṣàpèjúwe ilé náà gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ilé nlá èyí tó ṣé déédéé, Ó wá rọ́ àwọn ọlọ́pàá tó ń ṣiṣẹ́ ní àgbègbè Ozubulu àtí Ihembosi látí ríi dájú pé ààbò ẹ̀mí àtí dukia àwọn ènìyàn ní àgbègbè náà jẹ́ wọ́n lógún.

Nigba tí Kọmíṣọ́nà fún ilé kikọ́ tí Ìpínlẹ̀ náà, Honourable Paul Onyeka ń sọ̀rọ̀, ó sọ pé èyí jẹ́ ìdáhùn sí ìpè Gómìnà Soludo fún àwọn ọmọ Anambra látí darapọ̀ mọ́ Gómìnà látí ṣé ìdàgbàsókè ìpínlẹ̀ náà nítorí pé, ìjọba nìkàn kó lè dá ṣé è.

Ní àpá tirẹ, Olóyè Ikegwuonu ṣàlàyé pé wọ́n bá agọ́ Ọlọ́pàá náà jẹ́ lásìkò ìwọ́de #EndSARS l’ọdun 2020 àtí pé oún tí pinnu látí kọ́ ibùdó túntún mìíràn náà lẹyìn àtúnṣe tí kò bá ìgbà mú tí ìjọba ṣé fún àgọ náà.

Alákóso Àgbà tí àgbègbè Ozubulu, Engineer Chris Ononuju, gbóríyìn àti ìdúpẹ́ fún Olóyè Ikegwuonu fún ìgbìyànjú alailẹgbẹ rẹ̀ láti mú ìdàgbàsókè bá gbogbo àgbègbè náà, Ó sí dúpẹ lọ́wọ́ àwọn mìíràn tó ń ṣé irúfẹ́ iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ ní àgbègbè náà.

Comments are closed.

button