Àwùjọ Àwọn Ònímọ̀-ẹrọ́ tí Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà (Nigeria Society of Engineers NSE), tí pé fún ìwúlò Ìwé-ẹrí kẹ́sàn (Grade 9) fún iṣẹ́ ìjọba Nàìjíríà, pàápàá jùlọ ní àwọn ìpínlẹ̀.
Ààrẹ Obìnrin Àkọ́kọ́ tí NSE, Ìyááfín Margaret Oguntala tó pé ìpè náà lásìkò ayẹyẹ nílùú Abuja.

Làkókò tó ń sọ̀rọ̀ rẹ̀, Ìyááfín Oguntala sọ pé àkòrí fún àkókò rẹ̀ ní “Àtúnṣe NSE fún ìdàgbàsókè àti ìlọsíwájú tí ìmọ-ẹrọ́ (Engineering) ní Nàìjíríà.”

O fí kún pé òún yóò ṣé ìdàgbàsókè ìmọ̀-ẹrọ́, ṣé àgbégá àwọn ìmọ túntún tí ìmọ-ẹrọ́ àti ṣé ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tí yóò ṣé ìlọsíwájú ìdàgbàsókè iṣẹ́ náà.
Ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Alàgbà Godswill Akpabio tó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ NSE nígbà tó ń sọ̀rọ̀, wípé iyansipo Iyaafin Oguntala gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ Obìnrin àkọ́kọ́ láwùjọ jẹrí sí pé ilé-iṣẹ́ ìmọ-ẹrọ́ náà f’ayé gbá àwọn Obìnrin.
Ààrẹ ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà náà ní ìgbákejì rẹ̀ Barau Jibrin ṣójú fún .