Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn Ajínígbé Tí Tú Àwọn Ọmọbìnrin Mẹ́rin Tí Wọ́n Jìgbé Sílẹ̀ Nílùú Abuja

251

Ìdùnnú nlà ṣubú l’ayọ̀ ní ilè wọ́n ní Abuja àti ìdílé wọ́n ní Ìpínlẹ̀ Kwara, bí àwọn ajínígbé tí tú àwọn ọmọbìnrin mẹ́rin tí wọ́n jí pẹ̀lú bàbá wọ́n ní ìbẹrẹ oṣù yìí.

Á gbọ́ pé àwọn ọmọbìnrin náà dé ilé wọ́n ní Abuja ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, ogún jọ́, Oṣù Kínní, ọdun 2024.

Àwọn òṣìṣẹ́ ààbò mú àwọn ọmọbìnrin náà lọ́ sí ilé wọ́n níbí tí àwọn ẹbí wọ́n tí tẹwọ gbá wọ́n.

Àwọn mẹ́rin náà ní Najeeba, ọmọ ilé-ìwé gíga ọdún kàrún tó ń kẹ́kọ́ lórí ‘Quantity Surveying,’ àbúrò rẹ̀ Nadherah, ọmọ ilé-ìwé ọdún kẹ́ta tó ń ká lórí ‘Zoology’, tí àwọn méjèèjì sí jẹ́ ọmọ Ilé-ẹ̀kọ́ gíga ‘Ahmadu Bello (ABU)’ Zaria àti àwọn Ìbejì wọ́n, Habeeba àtí Haneesa.

Wọ́n tí sàn owó ọgọrùn mílíọ̀nù (N100m) Náírà tí wọ́n gbé lè wọ́n, ṣùgbọ́n àwọn ajínígbé náà ó fí wọ́n sílẹ̀ fún ọjọ́ mélòó kàn tí wọ́n sí n dá ẹbí wọ́n láàmú titi dì alẹ̀ ọjọ́ Àbámẹ́ta.

Nínú àtẹ̀jáde kàn tí Sherifdeen Al-Kadriyah kàn fọwọ́sí, ẹbí náà dúpẹ lọ́wọ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà fún ìdúró tí wọ́n ní làkókò ìgbìyànjú àti ìpọ̀njù náà.

Comments are closed.

button