Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Tinubu Kí Festus Keyamo Kú Oríire Ọjọ́ìbí

342

Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu tí kí Olorogun Festus Keyamo tó jẹ́ Mínísítà fún ètò Ọkọ̀ Òfurufú àti ìdàgbàsókè Òfurufú lásìkò tó ń ṣé ayẹyẹ ọjọ́ìbí ọdún mẹ́rinlèlàádọta (54).

Nínú àtẹ̀jádé kàn tí Alukoro Ààrẹ, Ajuri Ngelale fọwọ́sí, Ààrẹ Tinubu gbóríyìn fún Olorogun Keyamo fún bó ṣé jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ àtìlẹ́yìn fún ìdájọ́ òdodo, òtítọ, àtí ìsọkan orílẹ̀-èdè.

Ààrẹ náà kí agbẹjọro náà tó ṣé àpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọkàn nínú àwọn tó gbìyànjú lórí ìṣàkóso réré àtí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà.


Olórí Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà náà gbóríyìn fún ifarabalẹ Ọ̀gbẹ́ni Keyamo lórí ojúṣe àtí iṣẹ́ takúntakun.

Ààrẹ Tinubu gbàdúrà ìlera, ọ̀gbọ́n àtí òye lórí àwọn iṣẹ́ ilú fún Olorogun Keyamo.

Comments are closed.

button