Ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣofin, Ọ̀gbẹ́ni Ahmad Lawan ti jáwé Olúborí nínú ìbò Sẹ́nétọ̀ fún Ẹkùn Àríwá Yobe, ní Ìpínlẹ̀ Yobe.
Àjọ INEC kéde rẹ̀ ní alẹ́ ọjọ́ Àìkú gẹ́gẹ́ bí ẹni tó jáwé Olúborí. pẹ̀lú ìbò 91,318. Ó fi ìbò yìí borí alátakò rẹ̀ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, ògbéni Bello Ilu tó ní 22,849 ìbò.
Ẹléèkeje irú rẹ̀ tí yóò wọlé nìyí sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin láti ọdún 1999, méjì àkọ́kọ́ fún ní tíkẹ̀ẹ̀tì sí ilé asojú sòfin, márùn ún tó kù sì fún ní ànfàní láti jẹ Sénétọ̀.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply