Àjọ ECOWAS Pe Ìpàdé Mìíràn Lóríi Ọ̀rọ̀ Àwọn Ológun Tí Wọ́n Fi Agbára Gba Ìjọba Ní Niger
George Ọláyínká Akíntọ́lá.
Alága Àwọn Olórí orílẹ̀-èdè àti Ìjọba ti Àjọ ECOWAS àti Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàíjíríà, Bola Ahmed Tinubu, ti pe àpéjọ kíákíá mìíràn láti sọ̀rọ̀ lóríi ipò òṣèlú ní orílẹ̀-èdè Niger.
Wọ́n pe ìpàdé náà lẹ́yìn ti ọ̀sẹ̀ kan tí wọ́n fún ìjọba ológun Niger láti dá ààrẹ Ijọba tiwa-n-tiwa tí wọ́n dìbò yàn, ọ̀gbẹ́ni Mohamed Bazoum padà sípò, tàbí kí wọ́n gbé ìgbésẹ̀ to lagbara lori àwọn ologun náà.
Oludari Ibaraẹnisọrọ, Àjọ ECOWAS, nínú ọ̀rọ̀ kan, ní Ọjọ́ Ajé, sọ pe àpèjọ náà yóò wáyé nílùú Abuja, ní Ọjọ́ Kẹwàá, Ọjọ́bọ̀, Oṣù Kẹjọ, ọdún 2023.
Kókó ọ̀rọ̀ ti àwọn oludari ECOWAS yóò máa sọ níbi àpèjo náà dá lórí ipò ìṣèjọba àti àwọn iṣẹlẹ to ṣele ni aipẹ yìí ní Niger.
Bí àwọn ààrẹ ṣe ń ṣe ìpàdé náà ni àwọn ọmọ ológun orílẹ̀-èdè Nàíjíríà naa ń ṣe ìpàdé lóri ọ̀nà tí wọn yó gbà yanjú ìṣẹ̀lẹ̀ náà ní ọ́fìsì wọn nílùú Abuja.
George Ọláyínká Akíntọ́lá.
Leave a Reply