Àtubọ̀tán Yíyọ Owó Ìrànwọ́ Epo Bẹntiro: Makinde Ṣe Àgbékalẹ̀ Ọ̀nà Àbáyọ Fún Àwọn Èèyàn Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́
Ní ọna láti mú kí ìdẹ̀rùn dé bá àwọn èèyàn Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ látàrí yiyọ ti Ìjọba Àpapọ̀ yọ owó ìrànwọ́ epo bẹntiro ati bi ohun gbogbo ṣe lè koko mọ́ ará ìlú, Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti ṣe àgbékalẹ̀ ìgbìmọ̀ Ẹlẹ́ni-Mẹ́ẹ̀dógún ún to yóò máa ṣe kokaari ìgbésẹ ọlọ́jọ́ pípẹ́ fún ìmúpadàsípò ọrọ ajé (Sustainable Action for Economic Recovery, SAfER).
Àtẹ̀jáde ti Akọwe Ìròyìn fún Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Sulaimon Olanrewaju fi síta lo sàlàyé pé, Gómìnà Makinde lo kéde àgbékalẹ̀ ètò yìí ni òpin ọsẹ tó kọjá láti mú ìdẹ̀rùn dé bá àwọn èèyàn Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ látàrí àtúnbọ̀tán owo ìrànwọ́ epo bẹntiro tí ìjọba àpapọ̀ yọ kúrò.
Gẹ́gẹ́ bí atẹjade náà ṣe ṣàlàyé, Ẹni tíì ṣe Olórí Òṣìṣẹ́ fún Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ṣẹgun Ogunwuyi ni yóò máa ṣe Alága, nígbà tí Kọmísánnà fún Ìsúná àti Ètò Ọrọ̀ Ajé ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ọjọgbọn Musibau Babatunde yóò máa ṣe Akọwe ìgbìmọ̀ náà.
Àwọn yòókù ní Kọmísánnà fún Ètò Ìnáwó, Akinola Ojo; Kọmísánnà fún Iṣẹ Àgbẹ̀ àti Ìdàgbàsókè Ìgbèríko, Olasunkanmi Olaleye; Kọmísánnà to n ṣàkóso Ìjọba Ìbílẹ̀ àti Oyè jíjẹ, Segun Olaiwola; Kọmísánnà fún Ìròyìn, Dọtun Oyelade; Olùdámọ̀ràn pàtàkì lórí ọ̀rọ̀ Oṣiṣẹ, Titilola Sodo.
Àwọn tó kù ní Oloye Bayo Lawal, Amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ Àgbà fún Gómìnà lórí gbogbo Iṣẹ; Alhaji Kolawole Gafar, Oluranlọwọ Àgbà lórí Ìnáwó, Ètò ìsúná àti Ètò Ọrọ̀ Ajé; Sunday Odukoya, Olùrànlọ́wọ́ Àgbà lórí Ètò Ààbò; Ololade Ajibola, Olùrànlọ́wọ́ Pàtàkì fún Iṣẹ́ Pàtàkì; Bíṣọ́ọ̀bù Daniel Oluwajimade, Aṣojú ẹgbẹ́ ọmọ lẹ́yìn Kristi, CAN; Alhaji Muniru Ogundipe, Aṣojú àwọn ẹlẹsin Mùsùlùmí; Ademola Babalola, Aṣojú ẹgbẹ́ Oníròyìn ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́; àti Jide Bamgbose, Aṣojú Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ará ìlú.
Makinde, nínú ìkéde náà jẹ kó di mímọ̀ pé, ètò SAfER yóò mu iderun dé bá àwọn aláìní, nígbà tí ètò náà yóò mú kí àwọn agbẹ ri ohun ògbìn lọpọ yanturu.
Ètò SAfER ni yóò wà lábẹ́ ìsòrí mẹfa wọnyii:
Ìgbòkègbódò Ọkọ: Ṣíṣe afikun òpópónà ti ọkọ n rìn, Àgbékalẹ̀ Ọkọ̀ Omituntun ti yóò máa rìn ìlú sí ìlú ní gbogbo ẹkùn àti ẹ̀dínwó owó ọkọ̀ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti arúgbó.
Ìpèsè Oúnjẹ: Àfojúsùn ètò yìí ni láti pèsè oúnjẹ fún àwọn Aláìní ti kò dín ní Ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba (200,000).
Ètò ààbò Oúnjẹ: Àfojúsùn ètò yìí ni láti pèsè ohun ọgbin láti ran àwọn àgbẹ̀ tó tó Ẹgbẹ̀rún Mẹ́wàá (10,000) lọwọ.
Iranlọwọ fún Àgbẹ Olokowo (Agropreneurial): Àfojúsùn ètò yìí ni láti rí sí pé àwọn ọdọ tí wọn ṣe okòwò iṣẹ́ Àgbẹ (Youth Entrepreneurship in Agribusiness Projects, YEAP) ti okòwò wọn sì ti f’ẹsẹ múlẹ̀ yóò ni ànfààní sí ètò ẹ̀yáwó tó tó (₦500,000,000) láti mú kí okòwò wọn gbèrú síi.
Ètò Koriya fún àwọn Olokowo Kékèèké (SME): Ìpèsè ẹ̀yáwó (₦5000,000,000) pẹ̀lú èlé diẹ fún àwọn Òhùntàjà, Oníṣe ọwọ́ àti àwọn olókòwò míràn.
Ìrànlọ́wọ́ Ètò Ìlera: Ètò yìí yóò máa pèsè ètò adojutofo ètò ìlera fún Ẹgbẹ̀rún lọ́nà Ọgọrun àwọn Aláìní. Bákan náà, ìjọba yóò sàn owó ọdún kan labẹ Àjọ to n rí sí ìpèsè adojutofo ètò ìlera ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, (Oyo State Health Insurance Agency, OYSHIA) fun gbogbo ẹni yìówù tó bá ti fi orúkọ sílẹ̀ lábé ètò yìí, ti ìjọba yóò sì tún san owó iforuko silẹ lábé ètò yìí fún gbogbo oṣiṣẹ-feyinti, ti gbogbo àwọn òṣìṣẹ́-feyinti to ti san owó yìí tẹlẹ yóò gba owo wọn padà.
Abiola Olowe
Ìbàdàn
Leave a Reply