Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko labẹ Oludari Ile Aṣofin naa, Aṣofin Mudashiru Ọbasa ti fọwọ si Ọgbẹni Adewuyi Adewale gẹgẹ bi Ayẹwe-owo-wo agba tuntun fun Ipinlẹ Eko ti Gomina Babajide fi ṣọwọ si wọn.
Igbimọ tẹẹkoto Ile Aṣofin naa lạbẹ Alaga wọn, Aṣofin Noheem Adams ati awọn ọmọ ẹgbẹ miiran bi, Aṣofin Setonji David, Aṣofin Nureni Akinsanya ati awọn miiran ṣayẹwo Ọgbẹni Adewuyi Adewale, ti wọn si fi mulẹ pe, o peregede.
Oludari Ile Aṣofin naa, Aṣofin Mudashiru Ọbasa ṣalaye idi ti wọn fi fun ẹni ti wọn yan naa lanfani lati ṣe ayẹwo rẹ ninu ipade ijiroro Ile
Ni ọjọ kẹtalelogun oṣu keje ọdun 2023 ni Gomina Babajide Sanwo-Olu ti Ipinlẹ Eko fi orukọ awọn Alakoso-agba tuntun ti ijọba fẹ yan sipo ranṣẹ si Ile Aṣofin Ipinlẹ Eko lati ṣayẹwo wọn ki wọn si fọwọ si wọn gẹgẹ bi o ṣe wa labẹ ofin pe, wọn kọkọ gbọdọ fi ọwọ si awọn eniyan ti wọn fẹ gba ipo ijọba bayii.
Lẹyin eyi ni gbogbo ọmọ ẹgbẹ Ile Aṣofin naa fi ohun ẹnu wọn dibo lati fọwọ si Ọgbẹni Adewuyi Adewale gẹgẹ bi Ayẹwe-owo-wo agba tuntun fun Ipinlẹ Eko.
Oludari Ile, Aṣofin Ọbasa wa pa a laṣẹ fun Akọwe-agba Ile, Amofin Ọlalekan Ọnafẹkọ lati kọwe ranṣẹ si Gomina pe, Ile ti fọwọ si ẹni ti o yan naa.
Leave a Reply