Àjọ Àgùnbánirọ̀ Kéde Ìyípadà Gbọ̀ngán Tí wọn yóò lò Fún Ipade Ọjọ Mọkanlelogun Awọn Àgùnbánirọ̀ Ní Ìpínlẹ̀ Plateau
Àwọn alakoso Àjọ Àgùnbánirọ̀ (NYSC) ti sọ fun gbogbo eniyan, paapaa julọ àwọn àgùnbánirọ̀ to n fojusọna pe gbọngan ètò ẹkọ ti àwọn Batch ‘B’ Stream One fún Ipinlẹ Plateau ti yipada lati eyi to wa ni Mangu si Waye Foundation, nipasẹ ile ẹkọ Buken Doi-Du ní ẹkun guusu, Ijọba ibiklẹ Jos, Ipinlẹ Plateau.
Eyi wa ninu alaye ti Oludari, iroyin ti Àjọ Àgùnbánirọ̀ (NYSC), Ogbeni Eddy Megwa.
Bótilẹ̀jẹ́pé àwọn iṣakoso ètò naa ko sọ idi kan pàtó fún iyipada gbọngan naa, eyi ko farapẹ ipo ti ààbò wa ni Agbegbe Ijọba Agbegbe Mangu ti Ipinle naa nitori iṣakoso Eto naa ti jẹ ki o han gbangba-gbàngbà pe aabo ati alafia àwọn Àgùnbánirọ̀ jẹ wọn logun.
Leave a Reply