Ilé iṣé to n mójú tó iṣé, ilé iṣé, ìwakùwà, àti ohun ògbìn,(NACCIMA)ti kí Ààrẹ Tinubu lórí ipò rẹ gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ alága fún ẹgbẹ́ ECOWAS.
Ààrẹ NACCIMA, Ọ̀gbẹ́ni Delẹ Oye ló ṣe ìkíni Oríire yìí ni ọjọ́ ìsinmi ní ìlú Eko, lẹ́yìn tí wọn Yan Ààre Tinubu sí ipò gẹ́gẹ́ bí alága fún ẹgbẹ́ ECOWAS.
O ní Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà n kópa gidigidi nínú ẹgbẹ́ ECOWAS àti àgbáyé
Ààrẹ NACCIMA wa sọ àwọn Ìpèníjà ti o yẹ kí wọn mọ́jú tó nínú ìpàdé ìtajà ti o ń bọ̀wá.
O ni àwọn oríṣiríṣi ìṣòro ni kò jẹ kí ètò ọ̀rọ̀ ajé gbèrú sí, ó ni bíi gbígbé owó lè ọjà, owó ọkọ̀, ìwà ìbàjẹ́ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ
O ní àwọn yóò ṣe àtìlẹ́yìn àti ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fún ìdàgbàsókè ètò ọ̀rọ̀ ajé.
Leave a Reply