Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Nàìjíríà Pàṣẹ Àbójútó Ààbò Tó Péye Fún Àwọn Élétó Ààbò Orílẹ̀-èdè Yìí

Ọlálékan Ọ̀rẹ́núgà

0 473

Ààrẹ Bola Tinubu tí pàṣẹ fún àwọn élétó ààbò lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti pèsè ààbò tó péye fún àwọn aráàlú ní gbogbo àgbègbè lórílẹ̀-èdè yìí.

Ààrẹ pàṣẹ fún àwọn élétó ààbò ní Ọjọ́rú nígbàtí Ó ṣé ìpàdé pẹ̀lú àwọn alákóso ààbò náà ní ilé-iṣẹ́ Ààrẹ, Abuja.

Ọgá àgbà àwọn ọmọ ogún Orílẹ̀-èdè yìí Lucky Irabor, sọ pé wọ́n yóò ṣé gbogbo òun tí Ààrẹ fẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà. Ó sọ èyí dì mímọ Nígbàtí o ń bá àwọn oníròyìn Ilé-iṣẹ́ Ààrẹ sọrọ ní ìparí ìpàdé náà.

O sọ pé àwọn alákóso ààbò ṣe àlàyé fún Ààrẹ lórí ipò ààbò ní gbogbo àgbègbè orílẹ̀-èdè yìí atí káàkiri àgbáyé.

Olùdámọ̀ràn ààbò lórílẹ̀-èdè náà, Major General Babagana Monguno, tí ó ti fẹ̀yìn tì, tún bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀.

Tún kà nípa:Ààrẹ Tinubu Ń Ṣé Ìpàdé Pẹ̀lú Àwon Olórí Ààbò

Monguno sọ pé Ààrẹ mọ́ rírí àwọn irúbọ tí àwọn ológun àti àwọn ilé-iṣẹ́ ààbò mìíràn tí ṣé sí ààbò orílẹ̀-èdè náà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button