Take a fresh look at your lifestyle.

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Nasarawa Fẹ́ kọ́ NIPR Yunifásitì

118

 

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Nasarawa ti sọ pé àwọn ètò ń lọ lọ́wọ́ láti kọ́ Ilé-ẹ̀kọ́ Ìbáṣepọ̀ Gbogbogbòò ti Nàìjíríà ” NIPR University sí ìpínlẹ̀ náà.

Gómìnà Abdullahi Sule ṣe ìfihàn náà nígbà tí ó gba àwọn aṣojú láti ilé ise Voice of Nigeria, VON tí Olùdarí Àgbà ń darí rẹ̀, ní ilé ìjọba ní Lafia ti n se olú ìlú ìpínlẹ̀ náà.

Gómìnà náà sọ pé Yunifásítì náà yóò kọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ni ìbáṣepọ̀ gbogbogbòò tí wọ́n lè tako àìtọ́, dáàbò bo ìjọba tiwantiwa àti láti ṣàkóso ààbò dáradára.

“Yóò mú kí àwọn oníròyìn àti àwọn olùbánisọ̀rọ̀ dàgbà nípa ṣíṣẹ̀dá àkójọ àwọn onímọ̀ nípa ìbáṣepọ̀ gbogbogbòò tí ó ní ìmọ̀ tí ó ń ṣàtìlẹ́yìn fún ìdàgbàsókè ọrọ̀ ajé àti ìdókòwò láti òkè-òkun,” Gómìnà Sule sọ eyi.

Gómìnà Sule ṣàlàyé bí ó ṣe ń mú àwọn aráàlú ṣiṣẹ́ kí ó tó bẹ̀rẹ̀ àwọn iṣẹ́ akanse tí ó ní ipa tààrà lórí àwọn ènìyàn.

Ó tọ́ka sí agbègbè Mararraba níbi tí àwọn ọ̀daràn ti máa ń gbé, èyí tí ó yí padà sí ibi tí ó dára jù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ àkànṣe tí àwọn ènìyàn ń ṣe.

Gómìnà dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn aṣojú ile ise VON fún ìbẹ̀wò sí ìpínlẹ̀ rẹ̀, pàápàá jùlọ Olùdarí Àgbà tí ó ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ń gòkè lọ láti ṣe àṣeyọrí ńlá yìí.

Ó fi dá Olùdarí Àgbà, Voice of Nigeria, lójú pé òun yóò ṣe àtìlẹ́yìn fún un láti kọ́ ìbáṣepọ̀ tó dára láàrín ìjọba rẹ̀ àti VON.

Olùdarí Àgbà, Voice of Nigeria, Jibrin Baba Ndace, yin ètò ìjọba ìpínlẹ̀ láti kọ́ NIPR Yunifásítì , ó sì tẹnu mọ́ pé, Gómìnà gbà pé àjọṣepọ̀ gbogbo ènìyàn ló ṣe pàtàkì ní gbogbo ẹ̀ka àwùjọ.

Ó yin Gómìnà Sule fún àṣeyọrí tó hàn gbangba tí a kọ sílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ náà, ó tẹnu mọ́ bí àwọn olùgbé ṣe gbádùn láti inú èrè ìjọba tiwantiwa.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button