Ààrẹ Faransé lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, Emmanuel Macron ti ní ìdá méjìdín-lọ́gọ́ta-ó-lé-díẹ̀ ìbò nínú ìdìbò ààrẹ,tí ó sì ṣẹ́gun olùdíje ti National Rally Marine, Le Pen, tí òhun ní ìbò ìdá oókànlé-lógójì-ó-lé-díẹ̀.
Gẹgẹ bi awọn abajade lati Ile-iṣẹ iṣiroorilẹ-ede Faranse ti o ṣafihan rẹ ni ọjọ aje,abajade naa fẹẹ dabi ibo Macron ni ọdun 2017, nigbati o jawe olubori pẹlu ida ookanle-lọgọta,ti Le Pen si ni ibo ida mẹtale-lọgbọn-o-le-diẹ ni ọdun marun sẹhin.
Ida mejidin-lọgbọn ti o lodi si ida mẹẹdọgbọn ni ko dibo ni ọdun 2017, ti o jẹ ida ti o kere julọ ninu itan idibo Aarẹ Faranse gbogboogbo lati ọdun 1969.
Leave a Reply