Makinde Ṣèlérí Láti Ṣe Àfọ̀mọ́ Àṣà To Níí Ṣe Pẹ̀lú Àyíká Àti Àmójútó Ìdọ̀tí: Ó Búra Fún Aderinto Gẹ́gẹ́ Bíi Kọmíṣọ́nnà Àyíká
Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti ṣèlérí
pé ìṣèjọba rẹ̀ yóò dojú ìjà kọ àwọn àṣà eléyìí tí àwùjọ ti jinlẹ̀ nínú rẹ̀ lórí ayíká àti àmójútó ìdọ̀tí ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, fún ànfàní gbogbo ará ìlú.
Gómìnà ló sísọ lójú ọ̀rọ̀ yìí lásìkò tó n búra fún Kọmíṣọ́nnà tuntun fún ọ̀rọ̀ Àyíká àti Ohun Àlùmọ́nì ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Ademola Aderinto ní gbàngàn ìgbìmọ̀ àwọn aláṣẹ Gómìnà ni Sekiteriati Ìjọba tó kalẹ̀ sí Agodi ní ìlú Ìbàdàn, tii ṣe olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni Ẹkùn Gúsù Ìwọ̀ Oòrùn Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìbúra, gómìnà jẹ́wọ́ pé púpọ̀ ṣi kù tí ìjọba rẹ̀ gbọ́dọ̀ ṣe nípa àmójútó ìdọ̀tí àti ọ̀rọ̀ ayíká, tó sì tẹnu mọ́ pé òun ni ìdánilójú pé ayípadà rere yóò wáyé kí ìṣèjọba rẹ̀ tó tẹnubọdò.
Síbẹ̀, Gómìnà fi àsìkò náà sọ pé àjọṣe àti ìfọwọ́sowọpọ̀ àwọn olùgbé Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ṣe pàtàkì fún àṣeyọrí ìgbésẹ̀ yìí. Nígbà tó kì Kọmíṣọ́nnà tuntun fún ìyànsípò rẹ̀, Gómìnà dúpẹ́ lọwọ́ Ilé Aṣòfin Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fún fífi orúkọ rẹ̀ sílẹ̀ lẹ́yìn ayẹ̀wò pípé.
Gómìnà Makinde rọ Kọmíṣọ́nnà tuntun láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, nígba tó ṣàlàyé pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé àkókò péréte ló kù kí ìṣèjọba rẹ̀ kásẹ̀ nílẹ̀, ó jẹ kí Kọmíṣọ́nnà náà mọ̀ pé o sí lè mú ìyàtọ̀ tó lágbára dé bá ọ̀rọ̀ ayíká àti àmójútó ìdọ̀tí pẹ̀lú àsìkò díẹ̀ tó wà ní ìkáwọ́ rẹ̀.
Nígbà tó ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìbúra rẹ̀, Kọmíṣọ́nnà Ayíká àti Ohun Alumọni sọ pé ìjọba yóò kojú àwọn ìṣòro tó jọ mọ́ àmójútó ìdọ̀tí ayíká, ìgbésẹ̀ lórí ìyípadà oju-ọjọ́ (climate action) àti ààbò ayíká.
Aderinto wà fi àsìkò náà rọ àwọn ènìyàn Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ìjọba, kí wọ́n sì gba ìwà ìmọ́tótó láàyè, àbò ayíká àti ṣíṣe ìdọ̀tí lọ́jọ̀ sí ibi tó yẹ gẹ́gẹ́ bí ìlànà òfin.
Abiola Olowe
Ìbàdàn