Ọ̀gá Àgba Adarí Ìṣòògùn, CMD, ti gbọ̀ngàn ilé ìwòsàn Ìkọ́ni ti ilé Ẹ̀kọ́ Gí́ga Fáfítì Ọbafemi Awolọwọ , OAUTHC, Ilé-Ifẹ̀, Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun , Gúsù- Ilà Oòrùn, Nàìjíríà, Ọ̀jọ̀gbọ́n John Okeniyi ti ṣàlàyé pé àwọn alákòóso ti mú wìwà láláàfíà àwọn òṣìṣẹ́ lọ́kúnkúndùn kí wọ́n ó le ṣiṣé dáradára.
Okeniyi sọ eyi di mimọ nigba ti o n gba awọn ọmọ ẹgbẹ akẹkọ ile iwe giga CMS nigba kan ri lalejo, ni Ile-Ifẹ, ní ọjọ́ Ẹtì.
CMD naa wa wa sọ pe awọn akitiyan leyi ti o mọ ṣiṣatunṣe lori ipo iṣiṣẹ, igbega ati gbigboriyin fun iṣiṣẹ to tawọn yọ n lọ lọwọ labẹlẹ.
Okeniyi wa tun ṣalaye pe oun gun ori oye nigba ti laasigbo wa ninu iṣẹ wọn nipasẹ fifunni niṣẹ lọna aitọ, leyi ti o si ti latunṣe bayii.
“A ti ṣatunṣe lori iṣẹ wa, a ti ṣagbekalẹ idanwo agbega meji. Awọn oṣiṣẹ to to irinwo lo kọ alakọọkọ, ti awọn oṣiṣẹ ẹdẹgbẹrin -o -din -mẹrin-le-lọgọrin si ti gba igbega lori bi wọn ṣe ṣe daradara si, ni ọdun keji,” o sọ bayii.
O tun wa fidiẹ mulẹ pe awọn oṣiṣẹ ki nilo lati maa gba ọna ẹburu ki wọn to gba igbega, ti o si ni awọn oṣiṣẹ kekere to to ọgọrun kan gan an ti gba igbega si ipo giga.