Take a fresh look at your lifestyle.

Òjò tí ó lágbára kan gbẹ̀mí ènìyàn méje ní Mogadishu

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

84

Ó kéré jù, ènìyàn méje ti pàdánù ẹ̀mí wọn ní agbègbè méjì Mogadishu, nígbàtí ojó àgbàyanu kan rọ̀ tí ó sì fa omí yalé ní Ilà Oòrùn Áfíríkà ní ọjọ́ Ẹtì, gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ ìjọba kan ṣe sọ.

 “A ti fidiẹ mulẹ pe ó kéré jù, ènìyàn méje ti pàdánù ẹ̀mí wọn, ti obinrin meji si wa lara wọn. Ojo tun da ile mẹsan an wo ti o si wọ inu ile igba,” Saleh Hassan, ti o jẹ agbẹnusọ fun Olori ilu Mogadishu, sọ bayii.

Ẹbi Somalia kan wọnu igbara omi naa,nigba ti wọn sa lẹyin ti ojo oru naa da ile wọn wo, ni agbegbe Wadajir ti Mgadishu.

Omiyale naa ba awọn ohun amayedẹrun ni olu ilu Somalia jẹ, leyi to fi dori bii opopona nla mẹfa, ti ko si jẹ ki lilọ bibọ o rọrun ni olu ilu, gẹgẹ bi Hassan ṣe sọ.

Lara awọn to padanu ẹmi wọn ni ọdọmọkunrin kan ti wọn ri oku rẹ ni ọkan lara awọn ọna ti o ti bajẹ ni Abamẹta.

Comments are closed.

button