Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti kí Ayirimi Emami, ẹni tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn adarí Itsekiri, oníṣòwò, àti olùṣàánú, fún àjọyọ̀ àádọ́ta ọdún rẹ̀.
Ninu alaye kan lati ile iṣẹ Aarẹ, Aarẹ gboriyin fun Emami fun awọn ipa ifarada rẹ̀ si idagbasoke orilẹ-ede, akitiyan rẹ lori iṣagbelarugẹ alaafia, idaabobo awọn amayedẹrun pataki epo ilẹ ati gaasi, ati imuduro isokan ati iduroṣinṣin ni agbegbe Niger Delta.
“Oloye Emami ti ṣe afihan ifarabalẹ ti ko ruju ninu ipa ti o ko ni orilẹ-ede nipasẹ iṣẹ rerẹ ati ipinnu rẹ si idaabobo ati imuduro awọn ohun elo agbara pataki Naijiria,” Aare naa pe akiyesi si eyi.
Aarẹ Tinubu wa funra rẹ dupẹ fun atilẹyin ọlọjọ pipẹ ti Emami ti n ṣe, ti o si tun mẹnuba iṣootọ ati atilẹyin lasiko pataki iṣelu, pẹlu idibo Aarẹ ọdun 2023.
“ Mo dupẹ lọwọ Oloye Emami fun atilẹyin rẹ fun mi ati iyawo mi, Arabinrin Akọkọ Sẹnetọ Oluremi Tinubulati ọdun yii— ọmọ arimuyangan Ilẹ Itsekiri; lati ọdun yii fun bi o ti duro tiwa ki idibo to bẹrẹ ati lasiko idibo ọdun 2023,” Aarẹ sọ bayii.
Aarẹ wa gba adura pe ki ọlọrun tunbọ fun Oloye Itsekiri ni alaafia ati ọpọlọpọ ọdun alayọ laye ki o si lẹ ṣe ojuṣe rẹ fun awọn eniyan Itsekiri ati orilẹ-ede lapapọ.