Take a fresh look at your lifestyle.

Àjíǹde: Gómìnà pè fún ìgbàmọ́ra, Ìrẹ́pọ̀ kí Nàìjíríà lè dára jùlọ

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

87

Gómìnà Ìpínlẹ Anambra, Ọ̀jọ̀gbọ́n Chukwuma Soludo, kí àwọn ọmọ lẹ́yìn Krísítì kú ọdún Àjíǹde, tí ó sí pè fún ìgbàmọ́ra, Ìrẹ́pọ̀ kí Nàìjíríà lè dára jùlọ.

Ninu afiranṣẹ kan lati ọdọ akọwe awọn Akọroyin Kirisitiẹni Aburime rẹ, Gomina Soludo gboriyin fun awọ Kirisitiẹni fun ifọkansin, ti o si rọ wọn lati kọ iwa aimọtaraẹni nikan Jesu Kirisiti lasiko Ajinde yii.

Soludo wa ṣalaye pataki Ajinde ni ṣiṣe agbelarugẹ iyi ìgbàmọ́ra, irẹlẹ, ati atunṣe, ti n tẹnumọ iwulo fun ifarada ati ibagbepọ alafia ni Naijiria.

Gomina tun wa sọ pe pipese awujọ to lalaafia ati ilọsiwaju jẹ oun logun ni ipinlẹ Anambra, nibiti awọn eto imulo ijọba ti ṣe igbelaruge iṣọkan lawujọ ati awọn anfani ọrọ aje fun gbogbo eniyan.

Soludo wa gbadura fun idunu ati atunbi ninu ọdun Ajinde, ti o si ni ireti fun saa tuntun aṣeyọri ati iṣọkan ni Naijiria.

Comments are closed.

button