Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Tinubu Kẹ́dùn Ikú Ọba Akran Tí Badagry ‎

755

Ààrẹ Bola Tinubu tí fí ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn lórí ikú Oba tí Badagry, Wheno Aholu Menu-Toyi I, Ọba Babatunde Akran, tí ó kú ní ọjọ́ Ajé ní ọmọ ọdún mọkándínlàádọ́rùn (89).

‎Nínú ìfiránṣẹ́ ìkíni tí Olùdámọ̀ràn Pàtàkì fún Ààrẹ lórí Ìròyìn àti Ìlànà, Ọ̀gbẹ́ni Bayo Onanuga fi ránṣẹ́, Ààrẹ náà kẹ́dùn fún Ìjọba àti àwọn ènìyàn Ìpínlẹ̀ Èkó, Ìgbìmọ̀ Àṣà Ìpínlẹ̀ Èkó, Ìgbìmọ̀ Àwọn Olóyè Badagry, àti àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Ìlú Badagry lórí Ọba tó wàjà.

‎Ààrẹ Tinubu ṣàpèjúwe Ọba Babatunde gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ìran àti ète tó fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ìtọ́sọ́nà tó dúró ṣinṣin fún ohun tó ju ogójì ọdún lọ, tó ń mú ìṣọ̀kan, ìfaradà àti àṣeyọrí wá káàkiri ìjọba náà.

Comments are closed.

button