Take a fresh look at your lifestyle.

Ìdìbò gómìnà Kogi : “A ní olùdíje tó dára, ẹ yẹra fún ìwà ipá” – Ǵomìnà Bello

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 195

Gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi, Yahaya Bello ti gba àwọn olólùfẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC), nímọ̀ràn láti yẹra fún ìwà ipá, nítorí pé ẹgbẹ́ náà ní olùdíje tó dára, tí ó jẹ́ Usman Ododo fún Ìdìbò gómìnà ọjọ́ kọkànlá, oṣù kọkànlá.

Bello gba imọran yii ni Kabba ni ọjọ Abamẹta, nibi apejọ ipolongo ẹgbẹ naa, nibi ti o ti sọ pe oun ni ireti pe APC ati Ododo yoo jawe olubori ninu idibo naa pẹlu atilẹyin ọlọrun.

O tun wa tẹnumọ pe iwa ipa ati jagidijagan ko le ṣe anfaani fun ẹnikankan, fun idi eyi o wa rọ awọn ọmọ egbẹ APC ati awọn ololufẹẹ wọn lati ṣe suuru fun aṣeyọri idibo naa:

Ẹ jẹ ki a dojuti awọn ọta wa ati awọn alatako pẹlu suuru ati ọgbọn, leyi ti yoo bori ija ti wọn gbe koju wa.”

Bello wa bẹ awọn eleto aabo lati ṣe iṣẹ wọn bii isẹ ki alafia le jọba ki ibo to bẹrẹ, lasiko ati lẹyin ibo gomina naa.

Alaga igbimọ ipolongo Ododo, Minisita fun idagbasoke Irin, Ọmọ Ọba Shuaibu Abubakar-Audu, ti o kọkọ ba apejọ naa sọrọ, wa n rọ awọn eniyan Kabba ati gbogbo Iwọ Oorun agbegbe Kogi lati tu yaya tu yaya wa dibo fun Ododo fun itẹsiwaju.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button