Gómìnà Yahaya Bello ti Kogi ti fi ìkópa ọgbọọgba àti ìṣojú da awọn ọmọ egbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ni ipinlẹ naa loju ninu idibo gomina ọjọ kọkanla, oṣu Belu ti n bọ lọna yii.
Gómìnà Bello ṣe ipinnu yi lasiko ti o n gba Ọgbeni James Faleke lalejo.
Falake jẹ igbakeji oludije gomina fun ẹgbẹ oṣelu APC ni 2015, tẹlẹ ri ti o si jẹ alaga ọmọ ile igbimọ Aṣoju fun igbimọ Inawo lọwọ bayii.
Gómìnà wa n fidi ẹ mulẹ pe ninu APC, gbogbo ọmọ ẹgbẹ lo lanfaani lati ko ipa tirẹ ti ẹgbẹ fun.
Ṣiwaju, Faleke, ti o ko awọn olùkówọ̀ọ́ to lagbara dani lọ sibi àpèjọ naa, wa sọ fun gomina pe abẹwo awọn fihan gbangba pe awọn ti ṣetan lati siṣẹ ati ṣe ipolongo fun aṣeyọri oludije ẹgbẹ naa, Usman Ododo, ninu idibo gomina ọjọ kọkanla, oṣu Belu.
Leave a Reply