Aṣòfin tẹ́lẹ̀ rí gbóríyìn fún ìdájọ́ ilé-ejọ́ lórí ìdìbò gómìnà ní Zamfara
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ọmọ Aṣòfin Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ rí ti gbóríyìn fún ìdájọ́ ilé-ejọ́ lórí ìdìbò gómìnà tí ó gba Dauda Lawal, gẹ́gẹ́ bí gómìnà ìpínlẹ̀ Zamfara tí wọ́n dìbò yàn.
Bala Gamji ṣe igboriyin yii nigba ti o n fesi si idajọ ile ejọ ni ipinlẹ Sokoto laipẹ yii.
Gẹgẹ bi oṣe sọ, idajọ naa ṣe pataki, ti o si fidi ifẹ awọn eniyan mulẹ, ati igbagbọ ti wọn ni lori gomina Dauda ti ẹgbẹ oṣelu People Democratic, PDP to mu idagbasoke wa nipasẹ adari rere.
O wa sọ pe Gomina Dauda yoo tẹsiwaju lati mu iyipada rere ti ipinlẹ naa fẹ ninu iṣakoso fun idagbasoke ibiafẹde.
O tun wa tẹnumọ ipinnu rẹ lati tunbọ maa ṣatilẹyin fun gomina lati ri daju pe o mu ileri rẹ wa si ìmúṣẹ,
Aṣofin naa wa sọ pe idajọ naa yoo jẹ ibẹrẹ ọpọlọpọ idagbasoke si fun ipinlẹ Zamfara.
Leave a Reply