Take a fresh look at your lifestyle.

Ibùdó ìgbàni wọlé NYSC Borno ṣí padà lẹ́yìn ọdún mẹ́tàlá

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 241

Ibùdó ìgbàni wọlé Àgùnbánirọ̀, NYSC ti ìpínlẹ̀ Borno ti ṣí padà fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Àgùnbánirọ̀ tuntun, lẹ́yìn ọdún mẹ́tàlá látàrí láàsìgbò ọlọ́jọ́ gbọọrọ ní ìpínlẹ̀ náà.

Gomina ipinlẹ Borno, Ọjọgbọn Babagana Umara Zulum wa nibi ayẹyẹ ifilọlẹ ti o si ṣi ibudo igbani wọle NYSC 2023,ti awọn ẹgbẹ 2, Ikọ B,wọle fun sisin orilẹ ede baba wọn fun ọdun kan.

Zulum sọ fi idunnu rẹ han ti o si dupẹ lọwọ ọlọrun fun iru anfaani naa.

Gomina tun wa sọ pe asiko ọlọjọ gbọọrọ ti oun ti n duro de lati ni ajọṣepọ pataki pẹlu Ẹgbẹ Agunbanirọ (NYSC), fun ipinlẹ Borno tuntun ti wa dele bayii.

O wa tunbọ tẹnumọ pe ijọba oun mọ gbogbo elo eto iwa nidaradara ti oun yoo si ri pe awọn ọmọ Agunbanirọ tuntun yii gbadun ju awọn to ti wa si ipinlẹ naa tẹlẹ lọ.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button