Àjọ tó ń ṣètò ẹ̀gbin ní ìpínlẹ̀ Èkó, LAWMA tí sọ pé àwọn yóò bèrè sí ní tíì àwọn ilé tí wọ́n kò ní àpótí ìdọ̀tí ní Lagos Island àtí Lagos Mainland, bẹ̀rẹ̀ làti ọjọ keje oṣù keje ọdún 2023.
Èyí ló wáyé ṣáájú Ìkìlọ tí wọ́n tí sí àwọn àgbègbè náà ní oṣù méjì sẹyìn.
Olùdarí ètò ìnáwó tí LAWMA, Ọ̀gbẹ́ni Kunle Adebiyi, ń sọ́ èyí fún ìgbà ìkẹyìn nínú atẹjade kàn pé lẹyìn tí Ìkìlọ tí síwájú tẹ̀lẹ̀, àti tí fún wọ́n ní àyè láti rá àpótí ìdàlẹ̀nù tó péye.
Tún kà nípa:Hajj 2023: Gómìnà Èkó Kẹ́dùn Ikú Arábìnrin Àrìnrìn-àjò Sílẹ̀ Mímọ Mekka Kàn
Adebiyi mẹnuba pé wọ́n yóò ṣé ìkìlọ ìkẹyìn fún àwọn olùgbé tí kó tíì rà àwọn àpótí náà àti ṣé ìtọjú àgbègbè ní ìlànà tó bá òfin mú.
Ṣùgbọ́n ó tún ráwọ́ ẹ̀bẹ̀ sí àwọn aráàlú látí ṣé ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ìjọba Gómìnà Babajide Sanwo-Olu láti ṣé ìmọtótó àwọn àyíká dáradára, kí á sí máa ló àwọn òṣìṣẹ́ PSP.
Leave a Reply