Ààrẹ Bola Tinubu tí fọwọ́ sí dídádúró tí ìpín márùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún owó-orí “Excise Tax” lórí ilé-iṣẹ́ ìbánisọ̀rọ̀ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Ó tún ti fọwọ́sí ìdádúró owó-orí “Excise Duty” tí àwọn ilé-iṣẹ́ ilẹ̀ wà.
Olùdámọ̀ràn pàtàkì sí Ààrẹ, Dele Alake fí èyí lédè nínú àpéjọ kàn pẹ̀lú àwọn òníròyìn Ilé-iṣẹ́ Ààrẹ ní Ọjọ́bọ̀.
Alake sọ fún àwọn òníròyìn pé àwọn ìgbésẹ̀ ìwọ̀nyí jẹ́ ọkàn nínú àwọn ìwé àṣẹ mẹ́rin ti Ààrẹ fọwọ́sí.
Tún kà nípa:Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Wà Ní Ojú Ọ̀nà Tó tọ́ Sí Àṣeyọrí:Ààrẹ Tinubu.
Ó sọ pé èròngbà Ààrẹ lórí bí buwọ́lù àwọn ìwé àṣẹ náà ní látí ṣé àdínkù ọ̀wọn gógó oúnjẹ àti òun míràn tí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ń kojú pàápàá ní àgbègbè sí sàn owó-orí lọ́pọ́ àtí látí jẹ́ kí ayé dẹ́rùn fún àwọn oníṣòwò tó nífẹẹ látí orílẹ̀-èdè yìí d’owo pọ̀.
Ẹkùn rẹ̀rẹ̀ ìròyìn náà ń bọ̀ lọ́nà…
Leave a Reply