Take a fresh look at your lifestyle.

Makinde Kẹ́dùn Ìpapòdà Olùdásílẹ̀ Ìjọ CAC Oke-Agbara

0 226

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti kẹ́dùn ìpapòdà Olùdásílẹ̀ Ìjọ ‘Christ Apostolic Church’ , CAC Òkè-Agbára, to wà ní agbègbè Asi Bódìjà, ni ìlú Ìbàdàn, Wòlíì Michael Ojo Olowere, tí wọ́n mọ sí Baba Olowere, nígbà tó fi ikú rẹ wé àdánù nlá sí agbo Kristẹni àti Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lápapọ̀.

Gẹ́gẹ́ bíi iransẹ ìkíni ìbánikẹ́dùn eléyìí tí Akọwe ìròyìn fún Gómìnà Sulaimon Olanrewaju fọwọ́ sí, ni Gómìnà tí kẹ́dùn pẹ̀lú àwọn adarí Ìjọ CAC káríayé, Ẹgbẹ́ CAN, ẹka ti Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, àti gbogbo ẹbí Baba Olowere pátá. Ó wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ìpapòdà Olùdásílẹ̀ Ìjọ CAC náà dun àwon olólùfẹ́ rẹ̀ àti gbogbo ọmọ lẹ́yìn kristi ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Makinde fi Bàbá Olowere we ‘Baba Ìgbàgbọ’ àti ọ̀kan nínú àwọn Ọmọ ogun Ọlọrun to n wa ire tó sì sa ipá rẹ̀ fún ìlọsíwájú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lápapọ̀ nípasẹ̀ ádùrá àti ìlọ́wọ́sí. Ó wá gbàdúrà kí Olorun fún gbogbo ẹbí àti ojúlùmọ̀ ni okun láti gba ìṣẹ̀lẹ̀ náà mọ́ra.

 

Abiola Olowe
Ìbàdàn

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button