Àmúkúrò Àdínkù: Sẹ́nétọ̀ Ndume rọ NLC láti dá ìyanṣélódì tí wọ́n ń gbaradì fún dúró
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Adarí ilé-ìgbìmọ̀ Aṣòfin tẹ́lẹ̀ rí, Sénétọ̀ Mohammed Ali Ndume, ti rọ adarí ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ Nàìjíríà lápapọ̀ (NLC), láti dá ìyanṣélódì tí wọ́n ń gbaradì fún,tí yóò bẹ̀rẹ̀ ní Ọjọ́ọ́rú dúró.
Sẹ́nétọ̀ Ndume wá rọ adarí ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ láti padàsí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ àti yíyanjú ibi tí àríyànjiyàn bá wà,kí wọ́n tó rawọ́ lé ìyanṣélódì.
Sẹ́nétọ̀ Ndume, tí ó tún jẹ́ Adarí lápapọ̀ fún ẹgbẹ́ ìpolongo Akpabio fún adarí ilé-ìgbìmọ̀ Aṣòfin, tún wá rọ ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu, kí ó ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn adarí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ fúnra rẹ̀, kí ó sì jẹ́ kí wọ́n mọ àǹfààní tó wà nínú àmúkórò Àdínkù náà.
Leave a Reply