Take a fresh look at your lifestyle.

Ìyànlóyè: Betara kí Gbajabiamila, Akume kú oríire

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 252

Ẹni tó ń dupò adarí ilé-ìgbìmọ̀ Aṣójú ẹlẹ́kẹwàá, Aṣojú Muktar Betara Aliyu, ti kí adarí ilé ìgbìmọ̀ Aṣojú, Aṣojú tó tifẹ̀yìntì, Fẹmi Gbajabiamila, gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá àgbà fún àwọn òṣìṣẹ́ ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu, àti Sẹ́nétọ̀ George Akume gẹ́gẹ́ bí Akọ̀wé fún ìjọba àpapọ̀.

Betara, ẹni tí ó jẹ́ alága ilé fún ìnáwó, ṣàpéjúwe adarí ilé nínú ìfiránṣẹ́ oríire rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí, adarí fún gbogbo ènìyàn ní tòòtọ́, tí ìṣe rẹ̀ sí ọmọnìyàn yóò ran àjọṣepọ̀ iṣẹ́ rere rẹ̀ pẹ̀lú àwọn aláṣẹ àti aṣòfin.

Ó wá sọ pé ààrẹ Tinubu ti yan ẹni tí ó dára jùlọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá àgbà fún àwọn òṣìṣẹ́ ààrẹ, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrírí nínú iṣẹ́ aṣòfin, ìṣadarí àti ìsòdodo.

Nígbà tí ó ń ṣàjọyọ̀ pẹ̀lú adarí ilé, ó wá gbàdúrà pé kí ọlọ́run fún un ní ọgbọ́n àti ààbò láti kó ipa tirẹ̀ nínú ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button