Àjọ NYSC ti bèrè fún ààbò tó péye fún àwon àgùnbánirọ̀ wọn lakoko ìdìbò yíyan Gómìnà àti asojú ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ tí yóò wáyé lóòní ọjọ́ kejidinlogun oṣù kẹta ọdún 2023.
Ọ̀rọ̀ yìí wáyé nínú àtẹjáde láti ọwọ́ Adarí àti alukoro Àjọ NYSC, Ọ̀gbẹni Eddy Megwa.
Adarí àgbà pátápátá fún àjọ NYSC dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn òṣìṣẹ́ elẹ́tò ààbò fún Ìbáṣepọ̀ àti àtìlẹ́yìn wọn fún àwọn Àgùnbánirọ̀ ni ìpínlẹ̀.
Ó ni ìpalẹ̀mọ́ ìdìbò yìí jé ànfààní lati mu awọn àgùnbánirọ̀ tẹ sí òfin àti ìlànà ètò ìdìbò èyí tí yóò mú àlàáfíà àti ìrọ̀rùn wa.
Leave a Reply