Take a fresh look at your lifestyle.

ÁÀh! Ó Se ! Ọkọ̀ Ọ̀fúrufú Kọlu Òpó Iná Lẹ́bàá Washington

0 356

Ọkọ̀ Ọ̀fúrufú kékeré kan kọlu òpó iná n’lá ní agbegbe Montgomery County ní Maryland, ní ibùsọ̀ ọgbọ̀n ṣí àríwá
Washington, D.C ní alẹ́ ọjó Àìkú tó sì fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ àìsí iná.

Àwọn panápaná àti adólàà ẹ̀mí ti Montgomery County sọ wípé Ọkọ̀ Òfurufú náà já lulè ní nkàn bí agogo márùn-uún àbọ̀ -5.30 p.m. (2230 GMT) ní ibi tí kùrukùru ti gbojú ọjọ́ tí ó sì tutù.

Ọkọ̀ òfurufú náà léfòó sí òkè ni orí òpó tó ń gbé iná tó ga tó ẹsẹ̀ bàtà ọgọrùn-ún láti ilẹ̀ pẹ̀pẹ̀. Eléyìí fa àìsí iná fún oníbárà iná ẹgbẹ̀rún lọnà ọgọ́fa bí Ilé Iṣẹ́ Pepco, ti Washington se sọ.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà ló dí pa, tí iná ojú ọ̀nà kòsì ṣiṣẹ́. Panápaná syo wípé àwọn ènìyàn méjì ló wà nínú ọkọ̀ ofuriufu ọ̀hún sùgbọ́n wọn kò tí kú.

Olórí adólàà èmi, Scott Goldstein láti Montgomery County ti wà níbè tí ó ṣì n pe ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ àwọn tó lùgbàdí ìjànbá náà lóòrèkóòrè .

Goldstein sọ wípé, wọ́n níláti kọ́kọ́ yọ ọkọ̀ Ọ̀fúrufú náà kí wọ́n gba ènìyàn tó wà nínú rẹ là.

Bí àjọ FAA se sọ, ọkọ̀ Ọ̀fúrufú Mooney M20J ń bọ̀ wá láti Westchester, New York, ó pan dandan fún láti balẹ̀ ní pápákọ̀ Montgomery.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

 

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button