Olùdarí Àgbà fún Báńkì fún Iṣẹ́ Àgbẹ̀, Ayo Sotinrin ti gbóríyìn fún àwọn ètò iṣẹ́ àgbẹ̀ àti oúnjẹ tí Ìyàwó Àkọ́kọ́ ní Nàìjíríà, Sẹ́nétọ̀ Oluremi Tinubu, ṣe, ó sì ṣàpèjúwe wọn gẹ́gẹ́ bí àwọn ìgbòkègbodò tó lágbára tó ń mú ààbò oúnjẹ lágbára sii àti tó ń kojú ounjẹ ti kò péye àwọn ọmọdé ní orílẹ̀-èdè yìí.
Sótinrin sọ ọ̀rọ̀ yìí nígbà tí Ìyàwó Àkọ́kọ́ gbà á lalejo ní ọ́fíìsì rẹ̀ ní gbọ̀ngán ààrẹ, Abuja.
Sótinrin tẹnu mọ́ ìfilọ́lẹ̀ Ètò apapọ̀ Báńkì fún Oúnjẹ Àwùjọ ti tó ń bọ̀, tí Ìyáàfin Tinubu kéde láìpẹ́ yìí, ó sọ pé ètò náà yóò “kojú ounjẹ ti kò péye láti orísun nípa gbígbé iṣẹ́ oúnjẹ tó ní agbára láti orísun lárugẹ.”
Gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ, “ìgbòkègbodò náà ni a ṣe láti rí i dájú pé a lè rí oúnjẹ tó ní peye, to sara loore gbà nígbàtí a sì ń mú kí àwọn ètò oúnjẹ tó ní péye láti agbègbè lágbára ní gbogbo orílẹ̀-èdè yii.”
Olùdarí Àgbà ti Bankii agbẹ̀ sọ pé òun wà ní ọ́fíìsì aya ààrẹ láti ṣe àgbékalẹ̀ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ìgbékalẹ̀ ètò àjọ “National Community Food Bank”.
Ó ní ìrètí pé àwọn ìran ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ń bọ̀ yóò ní ìlera tó péye.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san