Take a fresh look at your lifestyle.

Agbẹjọ́rò Ọmọ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Karimot Odebode Gba Ẹ̀bùn Àgbáyé Ti Taiwan

26

 

Agbẹjọ́rò ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kan, akéwì, àti olùgbèjà takotabo, Karimot Odebode, ti gba ebun ife agbaye alaye ẹlẹ́ẹ̀kọkàndinlọ́gbọ̀n-“29th Global Love of Lives Award” tí Chou Ta-Kuan Cultural and Educational Foundation, àjọ tí kìí ṣe ti ìjọba Taiwan (NGO) fún, ní ìbámu pẹ̀lú ìgbéjà rẹ̀ fún ẹ̀kọ́ àti ironilagbára àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin aláwọ̀ dúdú.

Aṣojú, Liu Yi-Ping, pẹ̀lú àwọn aṣojú láti Taiwan àti àwọn ará ìlú òkèèrè, ṣe àkíyèsí ayẹyẹ “Ìfẹ́ Ayé Àgbáyé ti Taiwan”, tí ó wáyé ní Ọ́fíìsì Ìṣòwò Taipei ní Nàìjíríà, ni aṣojú náà, Liu Yi-Ping, pẹ̀lú àwọn aṣojú láti Taiwan àti àwọn ará ìlú òkèèrè, ṣe bí wọ́n ṣe dara pọ̀ mọ́ ìtànkálẹ̀ agbára ìfẹ́ tí kò mọ ààlà.

Olùdásílẹ̀ ẹgbẹ́ NGO náà, Chou Chin-Hua, àti Alága, Guo Ying-Lan, ẹni tí ó ṣáájú àwọn aṣojú mẹ́fà ti “Taiwanese Life Warriors” sí Nàìjíríà, fún Odebode, agbẹjọ́rò kan láti Ibadan, Ìpínlẹ̀ Oyo, ní ẹ̀bùn náà pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Àjọ Overseas Community Affairs Council àti Ọ́fíìsì Ìṣòwò Taipei ní Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ètò náà gbé ìjíròrò àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ lárugẹ láti ìrandíran, àṣà, àti ẹ̀sìn, ó ń gbìyànjú láti dé gbogbo igun àgbáyé – títí kan àwọn ọmọbìnrin dúdú tí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ jùlọ nípa gbígbé ìṣọ̀kan, onírúurú, ìfọkàntán, àti ọ̀wọ̀ fún ara wọn lárugẹ.

Wọn ṣe àkíyèsí pé a mọ̀ Odebode gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára “Àwọn Ọ̀dọ́ tí ó ní Ìpalára jùlọ” ní Áfíríkà nítorí pé ó ní orúkọ “Agbẹjọ́rò-Akéwì Ìfẹ́-Àwùjọ Nàìjíríà” ní tòótọ́, ó ní o peregede julo láàrín àwọn tí a yàn kárí ayé tó sunmọ egberun merin-3,795, wọ́n sì fi ẹ̀bùn Ìfẹ́-Ayé Àgbáyé Kọkandínlọ́gbọ̀n (29th Global Love of Lives Award) láti ọwọ́ Chou Ta-Kuan Foundation ti Taiwan ní ọdún 2026 fún.

Ìpìlẹ̀ náà tún ṣe àtìlẹ́yìn fún Ayowole Academy of Arts, àti Land of Hope in Nigeria, nígbà tí ó ń fi ẹ̀dà Gẹ̀ẹ́sì ti iṣẹ́ Chang Kuo-Chu lẹ́yìn ikú rẹ̀, I Still Have One Leg, pẹ̀lú àwọn ẹ̀bùn láti Taiwan, láti fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ aláìní, àwọn akosemosẹ́ àti àwọn jagunjagun ẹ̀mí ní gbogbo orílẹ̀-èdè náà ní ṣìírí.

Àwọn ti wọn pè sì ibi idije náà ní; Karimot Odebode; Danish charity angel, Anja Ringgren Lovén; ati “Nigerian child artist”, Waris Olamilekan Kareem. Àwọn tó tún wà ní ọ́fíìsì ìṣòwò Taipei ni Olùdarí Ètò ti “Black Girl’s Dream Initiative” ní Fatimah Adebimpe to jẹ Olùdarí Iṣẹ́ Àgbékalẹ̀ náà, Foyinsaye Ejilola; àti Abdulateef Odebode, àbúrò ẹni tí wọ́n fún ní ẹ̀bùn náà.

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Comments are closed.

button