Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé Asòfin Èkó Fọwọ́ Sí Àdéhùn Àwon Ilé-isé Méjì Tí Yóò Máa Bá Ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkó Sisẹ́

28

 

Ilé Ìgbìmò Asòfin Ìpínlè Èkó ti fowó sí àdéhùn àwon Ilé-isé méjì tí yóò máa bá ìjoba Ìpínlè Èkó sisé láti túbò mú ìgbèrú bá èka ìmójútú ìdòtí àti èka ìrìnnà okò ilè.

Àwon Omo egbé Ile Asòfin náà fowó sí àdéhùn náà lójó Ajé (Monday) láàrin ìjoba Ìpínlè Èkó àti Ilé-isé Zoomlion Nigeria Limited lórí àmójútó ìdòtí, àti àdéhùn mìíràn láàrin ìjoba Ìpínlè Èkó àti Ilé-isé TSL Metroline Limited pèlú àdéhùn ríra àwon okò CNG egbèrún méjì àti fífi wón sisé.

Eléyìí ni ìgbésè tó tèlé àbájáde Ìgbìmò tèékótó eléni mérin tí Asòfin Gbóláhàn Yishawu jé Alága fún.

Asòfin Yishawu so pé ètò yìí yóò mú ìgbèrú bá isé àmójútó ìdòtí, síse àtúnse sí àwon ìdòtí yìí, yóò lè jè kí ìlera pípé wà láàrin ìlú, yóò tún pèsè isé fún òpò àwon olùgbé Ìpínlè Èkó, àti ànfàní orò-ajé ní ìbámu pèlú ìlànà èròngbà ìjoba Ìpínlè Èkó lórí ìmójútó àyíká àti ìlànà àgbáyé.

Àdéhùn yìí yóò mú ìgbèrú bá ètò ìrìnnà okò ilè ní ìlú Èkó, pàápàá àwon ònà tí èka ilé Isé LAMATA n se àkóso rè.

Nígbà tí ó n gbóríyìn fún Ìgbìmò tèékótó náà fún isé ribiribi tí wón se Asofin Bonu Solomon dábàá pé, kí wón pín àwon okò CNG yìí dógbadógba káàkiri àwon agbègbè ìjoba Ìbílè.

Léyìn ìfilólè àbájáde yìí ni Ilé Asofin lábé Olùdarí náà, Asòfin Mudashiru Obasá panipò fowó sí àbájáde Ìgbìmò náà.

Lánre Lagada-Abayomi.

Comments are closed.

button